Luk 4:16-30

Luk 4:16-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si wá si Nasareti, nibiti a gbé ti tọ́ ọ dàgba: bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si wọ̀ inu sinagogu lọ li ọjọ isimi, o si dide lati kàwe. A si fi iwe woli Isaiah fun u. Nigbati o si ṣí iwe na, o ri ibiti a gbé kọ ọ pe, Ẹmi Oluwa mbẹ lara mi, nitoriti o fi àmi oróro yàn mi lati wasu ihinrere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ. Lati kede ọdún itẹwọgba Oluwa. O si pa iwe na de, o tun fi i fun iranṣẹ, o si joko. Gbogbo awọn ti o mbẹ ninu sinagogu si tẹjumọ ọ. O si bẹ̀rẹ si iwi fun wọn pe, Loni ni Iwe-mimọ yi ṣẹ li etí nyin. Gbogbo wọn si jẹri rẹ̀, ha si ṣe wọn si ọ̀rọ ore-ọfẹ ti njade li ẹnu rẹ̀. Nwọn si wipe, Ọmọ Josefu kọ́ yi? O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o pa owe yi si mi pe, Oniṣegun, wò ara rẹ sàn: ohunkohun ti awa gbọ́ pe o ti ọwọ́ rẹ ṣe ni Kapernaumu, ṣe e nihinyi pẹlu ni ilẹ ara rẹ. O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si woli ti a tẹwọgbà ni ilẹ baba rẹ̀. Ṣugbọn mo wi fun nyin nitõtọ, opó pipọ li o wà ni Israeli nigba ọjọ woli Elijah, nigbati ọrun fi sé li ọdún mẹta on oṣù mẹfa, nigbati ìyan nla fi mu ká ilẹ gbogbo; Kò si si ẹnikan ninu wọn ti a rán Elijah si, bikoṣe si obinrin opó kan ni Sarefati, ilu kan ni Sidoni. Ati adẹtẹ̀ pipọ ni mbẹ ni Israeli nigba woli Eliṣa; kò si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ́, bikoṣe Naamani ara Siria. Nigbati gbogbo awọn ti o wà ninu sinagogu gbọ́ nkan wọnyi, inu ru wọn ṣùṣù, Nwọn si dide, nwọn tì i sode si ẹhin ilu, nwọn si fà a lọ si bèbe òke nibiti nwọn gbé tẹ̀ ilu wọn do, ki nwọn ba le tari rẹ̀ li ogedengbe. Ṣugbọn o kọja larin wọn, o ba tirẹ̀ lọ.

Luk 4:16-30 Yoruba Bible (YCE)

Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́. Wọ́n fún un ní ìwé wolii Aisaya. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé, “Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu mi nítorí ó ti fi òróró yàn mí láti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran; láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia, ati láti waasu ọdún tí Oluwa yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là.” Ó bá pa ìwé náà dé, ó fi í fún olùtọ́jú ilé ìpàdé, ó bá jókòó. Gbogbo àwọn eniyan tí ó wà ninu ilé ìpàdé tẹjú mọ́ ọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.” Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?” Ó sọ fún wọn pé, “Ní òtítọ́ ẹ lè pa òwe yìí fún mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn! Ohun gbogbo tí a gbọ́ pé o ṣe ní Kapanaumu, ṣe wọ́n níhìn-ín, ní ìlú baba rẹ.’ ” Ó tún fi kún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí wolii kan tíí ní iyì ní ìlú baba rẹ̀. “Òtítọ́ ni mo sọ fun yín pé opó pọ̀ ní Israẹli ní àkókò Elija, nígbà tí kò fi sí òjò fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ìyàn fi mú níbi gbogbo. A kò rán Elija sí ọ̀kankan ninu wọn. Ọ̀dọ̀ ẹni tí a rán an sí ni opó kan ní Sarefati ní agbègbè Sidoni. Àwọn adẹ́tẹ̀ pọ̀ ní Israẹli ní àkókò wolii Eliṣa. Kò sí ọ̀kan ninu wọn tí a wòsàn, àfi Naamani ará Siria.” Nígbà tí àwọn tí ó wà ninu ilé ìpàdé gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí gbogbo wọn. Wọ́n dìde, wọ́n tì í sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ibi tí ìlú wọn wà, wọ́n fẹ́ taari rẹ̀ ní ogedengbe. Ṣugbọn ó la ààrin wọn kọjá, ó bá tirẹ̀ lọ.

Luk 4:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé: “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, Nítorí tí ó fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìmúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́, láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.” Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.” Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?” Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ” Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní Israẹli nígbà ọjọ́ wòlíì Elijah, nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo; Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Elijah sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sarefati, ìlú kan ní Sidoni. Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Israẹli nígbà wòlíì Eliṣa; kò sì ṣí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Naamani ará Siria.” Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú Sinagọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi, Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé. Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrín wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.