Luk 4:14-21
Luk 4:14-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si fi agbara Ẹmí pada wá si Galili: okikí rẹ̀ si kàn kalẹ ni gbogbo àgbegbe ti o yiká. O si nkọni ninu sinagogu wọn; a nyìn i logo lati ọdọ gbogbo awọn enia wá. O si wá si Nasareti, nibiti a gbé ti tọ́ ọ dàgba: bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si wọ̀ inu sinagogu lọ li ọjọ isimi, o si dide lati kàwe. A si fi iwe woli Isaiah fun u. Nigbati o si ṣí iwe na, o ri ibiti a gbé kọ ọ pe, Ẹmi Oluwa mbẹ lara mi, nitoriti o fi àmi oróro yàn mi lati wasu ihinrere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ. Lati kede ọdún itẹwọgba Oluwa. O si pa iwe na de, o tun fi i fun iranṣẹ, o si joko. Gbogbo awọn ti o mbẹ ninu sinagogu si tẹjumọ ọ. O si bẹ̀rẹ si iwi fun wọn pe, Loni ni Iwe-mimọ yi ṣẹ li etí nyin.
Luk 4:14-21 Yoruba Bible (YCE)
Jesu pada sí Galili pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko. Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Gbogbo eniyan sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere. Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́. Wọ́n fún un ní ìwé wolii Aisaya. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé, “Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu mi nítorí ó ti fi òróró yàn mí láti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran; láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia, ati láti waasu ọdún tí Oluwa yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là.” Ó bá pa ìwé náà dé, ó fi í fún olùtọ́jú ilé ìpàdé, ó bá jókòó. Gbogbo àwọn eniyan tí ó wà ninu ilé ìpàdé tẹjú mọ́ ọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.”
Luk 4:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá. Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé: “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, Nítorí tí ó fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìmúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́, láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.” Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”