Luk 3:7-14
Luk 3:7-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li o wi fun ọ̀pọ awọn enia ti o wá lati baptisi lọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin iran paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀? Nitorina ki ẹnyin ki o so eso ti o yẹ fun ironupiwada, ki ẹ má si ṣe bẹ̀rẹ si iwi ninu ara nyin pe, awa ni Abrahamu ni baba: ki emi ki o wi fun nyin, Ọlọrun le gbe ọmọ dide fun Abrahamu ninu okuta wọnyi. Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná. Awọn enia si mbi i pe, Kini ki awa ki o ha ṣe? O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu. Awọn agbowode si tọ̀ ọ wá lati baptisi lọdọ rẹ̀, nwọn si bi i pe, Olukọni, kili awa o ha ṣe? O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe fi agbara gbà jù bi a ti rán nyin lọ mọ́. Awọn ọmọ-ogun si bère lọdọ rẹ̀, pe, Ati awa, kili awa o ṣe? O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe huwa ipá si ẹnikẹni, ki ẹ má si ṣe rẹ ẹnikẹni jẹ; ki owo onjẹ nyin to nyin.
Luk 3:7-14 Yoruba Bible (YCE)
Johanu ń sọ fún àwọn eniyan tí ó jáde lọ ṣe ìrìbọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀? Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má bẹ̀rẹ̀ láti máa rò ninu ara yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mò ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi. A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí. Nítorí náà, igikígi tí kò bá máa so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.” Àwọn eniyan wá bi í pé, “Kí ni kí a wá ṣe?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó bá ní dàńṣíkí meji, kí ó fún ẹni tí kò ní lọ́kan. Ẹni tí ó bá ní oúnjẹ níláti ṣe bákan náà.” Àwọn agbowó-odè náà wá láti ṣe ìrìbọmi. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, kí ni kí a ṣe?” Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe gbà ju iye tí ó tọ́ lọ.” Àwọn ọmọ-ogun náà ń bi í pé, “Àwa náà ńkọ́, kí ni kí a ṣe?” Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rù ba ẹnikẹ́ni láti lọ́ wọn lọ́wọ́ gbà, Ẹ má ṣe fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni. Ẹ jẹ́ kí owó oṣù yín to yín.”
Luk 3:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.” Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.” Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”