Luk 3:1-2
Luk 3:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdún kẹdogun ijọba Tiberiu Kesari, nigbati Pontiu Pilatu jẹ Bãlẹ, Judea, ti Herodu si jẹ tetrarki Galili, Filippi arakunrin rẹ̀ si jẹ tetrarki Iturea ati ti Trakoniti, Lisania si jẹ tetrarki Abilene, Ti Anna on Kaiafa nṣe olori awọn alufa, nigbana li ọ̀rọ Ọlọrun tọ̀ Johanu ọmọ Sakariah wá ni ijù.
Luk 3:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún kẹẹdogun tí Ọba Tiberiu ti wà lórí oyè, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ gomina Judia, tí Hẹrọdu jẹ́ baálẹ̀ Galili, tí Filipi arakunrin rẹ̀ jẹ́ baálẹ̀ Ituria ati ti agbègbè Tirakoniti, Lusaniu jẹ́ baálẹ̀ Abilene; Anasi ati Kayafa sì jẹ́ olórí alufaa. Johanu ọmọ Sakaraya gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní aṣálẹ̀ tí ó wà.
Luk 3:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene, tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù.