Luk 24:46-49
Luk 24:46-49 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Bẹ̃li a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi ki o jìya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu okú: Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ. Ẹnyin si ni ẹlẹri nkan wọnyi. Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalemu, titi a o fi fi agbara wọ̀ nyin, lati oke ọrun wá.
Luk 24:46-49 Yoruba Bible (YCE)
Ó wá tún sọ fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Mesaya gbọdọ̀ jìyà, kí ó sì jí dìde kúrò ninu òkú ní ọjọ́ kẹta. Ati pé ní orúkọ rẹ̀, kí á máa waasu ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọnyi. N óo rán ẹ̀bùn tí Baba mi ṣe ìlérí sí orí yín. Ṣugbọn ẹ dúró ninu ìlú yìí títí agbára láti òkè wá yóo fi sọ̀kalẹ̀ sórí yín.”
Luk 24:46-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: Kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú: Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ. Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí. Èmi yóò rán ohun tí Baba mi ṣe ìlérí sí yín: ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerusalẹmu, títí a ó fífi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”