Luk 24:46-48
Luk 24:46-48 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Bẹ̃li a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi ki o jìya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu okú: Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ. Ẹnyin si ni ẹlẹri nkan wọnyi.
Luk 24:46-48 Yoruba Bible (YCE)
Ó wá tún sọ fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Mesaya gbọdọ̀ jìyà, kí ó sì jí dìde kúrò ninu òkú ní ọjọ́ kẹta. Ati pé ní orúkọ rẹ̀, kí á máa waasu ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọnyi.
Luk 24:46-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: Kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú: Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ. Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.