Luk 24:30-34
Luk 24:30-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, bi o ti ba wọn joko tì onjẹ, o mu àkara, o sure si i, o si bù u, o si fifun wọn. Oju wọn si là, nwọn si mọ̀ ọ; o si nù mọ wọn li oju. Nwọn si ba ara wọn sọ pe, Ọkàn wa kò ha gbiná ninu wa, nigbati o mba wa sọ̀rọ li ọna, ati nigbati o ntumọ̀ iwe-mimọ́ fun wa? Nwọn si dide ni wakati kanna, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si ba awọn mọkanla pejọ, ati awọn ti mbẹ lọdọ wọn, Nwipe, Oluwa jinde nitõtọ, o si ti fi ara hàn fun Simoni.
Luk 24:30-34 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó ń bá wọn jẹun, ó mú burẹdi, ó súre sí i, ó bù ú, ó bá fi fún wọn. Ojú wọn bá là; wọ́n wá mọ̀ pé Jesu ni. Ó bá rá mọ́ wọn lójú. Wọ́n wá ń bá ara wọn sọ pé, “Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú wa lọ́kàn bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà, ati bí ó ti ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ fún wa!” Wọ́n bá dìde lẹsẹkẹsẹ, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati àwọn tí ó wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n péjọ sí, àwọn ni wọ́n wá sọ fún wọn pé, “Oluwa ti jí dìde nítòótọ́, ó ti fara han Simoni.”
Luk 24:30-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn. Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!” Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn, Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!”