Luk 24:13-16
Luk 24:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Si kiyesi i, awọn meji ninu wọn nlọ ni ijọ na si iletò kan ti a npè ni Emmausi, ti o jina si Jerusalemu niwọn ọgọta furlongi. Nwọn mba ara wọn sọ̀rọ gbogbo nkan wọnyi ti o ṣẹlẹ̀. O si ṣe, nigbati nwọn mba ara wọn sọ, ti nwọn si mba ara wọn jirorò, Jesu tikararẹ̀ sunmọ wọn, o si mba wọn rìn lọ. Ṣugbọn a rú wọn li oju ki nwọn ki o máṣe le mọ̀ ọ.
Luk 24:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan náà, àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń lọ sí abúlé kan tí ó ń jẹ́ Imausi. Ó tó bí ibùsọ̀ meje sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń bá ara wọn jíròrò lórí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Bí wọ́n ti ń bá ara wọn jíròrò, tí wọn ń bá ara wọn jiyàn, Jesu alára bá súnmọ́ wọn, ó ń bá wọn rìn lọ. Ṣugbọn ó dàbí ẹni pé a dì wọ́n lójú, wọn kò mọ̀ pé òun ni.
Luk 24:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀. Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀. Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ. Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.