Luk 24:1-7
Luk 24:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ kini ọ̀sẹ, ni kutukutu owurọ̀, nwọn wá si ibojì, nwọn nmu turari wá ti nwọn ti pèse silẹ, ati awọn miran kan pẹlu wọn. Nwọn si ba a, a ti yi okuta kuro li ẹnu ibojì. Nigbati nwọn wọ̀ inu rẹ̀, nwọn kò si ri okú Jesu Oluwa. O si ṣe, bi nwọn ti nṣe rọunrọ̀un kiri niha ibẹ̀, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ didan duro tì wọn: Nigbati ẹ̀ru mbà wọn, ti nwọn si dojubolẹ, awọn angẹli na bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá alãye lãrin awọn okú? Ko si nihinyi, ṣugbọn o jinde: ẹ ranti bi o ti wi fun nyin nigbati o wà ni Galili, Pe, A ko le ṣaima fi Ọmọ-enia le awọn enia ẹlẹsẹ lọwọ, a o si kàn a mọ agbelebu, ni ijọ kẹta yio si jinde.
Luk 24:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibojì, wọ́n mú òróró olóòórùn dídùn tí wọ́n ti tọ́jú lọ́wọ́. Wọ́n rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì, wọ́n kò rí òkú Jesu Oluwa. Bí wọ́n ti dúró tí wọn kò mọ ohun tí wọn yóo ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin meji kan bá yọ sí wọn, wọ́n wọ aṣọ dídán. Ẹ̀rù ba àwọn obinrin náà, wọ́n bá dojúbolẹ̀. Àwọn ọkunrin náà wá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú? Kò sí níhìn-ín; ó ti jí dìde. Ẹ ranti bí ó tí sọ fun yín nígbà tí ó wà ní Galili pé, ‘Dandan ni kí á fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan burúkú lọ́wọ́, kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu, ati pé kí ó jí dìde ní ọjọ́ kẹta.’ ”
Luk 24:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú ìkunra olóòórùn dídùn ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá. Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jesu Olúwa. Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n: Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn angẹli náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrín àwọn òkú? Kò sí níhìn-ín yìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Galili. Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.’ ”