Luk 24:1-34
Luk 24:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ kini ọ̀sẹ, ni kutukutu owurọ̀, nwọn wá si ibojì, nwọn nmu turari wá ti nwọn ti pèse silẹ, ati awọn miran kan pẹlu wọn. Nwọn si ba a, a ti yi okuta kuro li ẹnu ibojì. Nigbati nwọn wọ̀ inu rẹ̀, nwọn kò si ri okú Jesu Oluwa. O si ṣe, bi nwọn ti nṣe rọunrọ̀un kiri niha ibẹ̀, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ didan duro tì wọn: Nigbati ẹ̀ru mbà wọn, ti nwọn si dojubolẹ, awọn angẹli na bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá alãye lãrin awọn okú? Ko si nihinyi, ṣugbọn o jinde: ẹ ranti bi o ti wi fun nyin nigbati o wà ni Galili, Pe, A ko le ṣaima fi Ọmọ-enia le awọn enia ẹlẹsẹ lọwọ, a o si kàn a mọ agbelebu, ni ijọ kẹta yio si jinde. Nwọn si ranti ọ̀rọ rẹ̀. Nwọn si pada ti ibojì wá, nwọn si ròhin gbogbo nkan wọnyi fun awọn mọkanla, ati fun gbogbo awọn iyokù. Maria Magdalene, ati Joanna, ati Maria, iya Jakọbu, ati awọn omiran pẹlu wọn si ni, ti nwọn ròhin nkan wọnyi fun awọn aposteli. Ọ̀rọ wọnyi si dabi isọkusọ loju wọn, nwọn kò si gbà wọn gbọ́. Nigbana ni Peteru dide, o sure lọ si ibojì; nigbati o si bẹ̀rẹ, o ri aṣọ àla li ọ̀tọ fun ara wọn, o si pada lọ ile rẹ̀, ẹnu yà a si ohun ti o ṣe. Si kiyesi i, awọn meji ninu wọn nlọ ni ijọ na si iletò kan ti a npè ni Emmausi, ti o jina si Jerusalemu niwọn ọgọta furlongi. Nwọn mba ara wọn sọ̀rọ gbogbo nkan wọnyi ti o ṣẹlẹ̀. O si ṣe, nigbati nwọn mba ara wọn sọ, ti nwọn si mba ara wọn jirorò, Jesu tikararẹ̀ sunmọ wọn, o si mba wọn rìn lọ. Ṣugbọn a rú wọn li oju ki nwọn ki o máṣe le mọ̀ ọ. O si bi wọn pe, Ọ̀rọ kili ẹnyin mba ara nyin sọ, bi ẹnyin ti nrìn? Nwọn si duro jẹ, nwọn fajuro. Ọkan ninu wọn, ti a npè ni Kleopa, si dahùn wi fun u pe, Alejò ṣá ni iwọ ni Jerusalemu, ti iwọ kò si mọ̀ ohun ti o ṣe nibẹ̀ li ọjọ wọnyi? O si bi wọn pe, Kini? Nwọn si wi fun u pe, Niti Jesu ti Nasareti, ẹniti iṣe woli, ti o pọ̀ ni iṣẹ ati li ọ̀rọ niwaju Ọlọrun ati gbogbo enia: Ati bi awọn olori alufa ati awọn alàgba wa ti fi i le wọn lọwọ lati da a lẹbi iku, ati bi nwọn ti kàn a mọ agbelebu. Bẹ̃ni on li awa ti ni ireti pe, on ni iba da Israeli ni ìde. Ati pẹlu gbogbo nkan wọnyi, oni li o di ijọ kẹta ti nkan wọnyi ti ṣẹ. Awọn obinrin kan pẹlu li ẹgbẹ wa, ti nwọn lọ si ibojì ni kutukutu, si wá idá wa nijì; Nigbati nwọn kò si ri okú rẹ̀, nwọn wá wipe, awọn ri iran awọn angẹli ti nwọn wipe, o wà lãye. Ati awọn kan ti nwọn wà pẹlu wa lọ si ibojì, nwọn si ri i gẹgẹ bi awọn obinrin ti wi: ṣugbọn on tikararẹ̀ ni nwọn kò ri. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti oyé ko yé, ti o si yigbì li àiya lati gbà gbogbo eyi ti awọn woli ti wi gbọ́: Ko ha yẹ ki Kristi ki o jìya nkan wọnyi ki o si wọ̀ inu ogo rẹ̀ lọ? O si bẹ̀rẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wá, o si tumọ̀ nkan fun wọn ninu iwe-mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀. Nwọn si sunmọ iletò ti nwọn nlọ: o si ṣe bi ẹnipe yio lọ si iwaju. Nwọn si rọ̀ ọ, wipe, Ba wa duro: nitori o di ọjọ alẹ, ọjọ si kọja tan. O si wọle lọ, o ba wọn duro. O si ṣe, bi o ti ba wọn joko tì onjẹ, o mu àkara, o sure si i, o si bù u, o si fifun wọn. Oju wọn si là, nwọn si mọ̀ ọ; o si nù mọ wọn li oju. Nwọn si ba ara wọn sọ pe, Ọkàn wa kò ha gbiná ninu wa, nigbati o mba wa sọ̀rọ li ọna, ati nigbati o ntumọ̀ iwe-mimọ́ fun wa? Nwọn si dide ni wakati kanna, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si ba awọn mọkanla pejọ, ati awọn ti mbẹ lọdọ wọn, Nwipe, Oluwa jinde nitõtọ, o si ti fi ara hàn fun Simoni.
Luk 24:1-34 Yoruba Bible (YCE)
Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibojì, wọ́n mú òróró olóòórùn dídùn tí wọ́n ti tọ́jú lọ́wọ́. Wọ́n rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì, wọ́n kò rí òkú Jesu Oluwa. Bí wọ́n ti dúró tí wọn kò mọ ohun tí wọn yóo ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin meji kan bá yọ sí wọn, wọ́n wọ aṣọ dídán. Ẹ̀rù ba àwọn obinrin náà, wọ́n bá dojúbolẹ̀. Àwọn ọkunrin náà wá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú? Kò sí níhìn-ín; ó ti jí dìde. Ẹ ranti bí ó tí sọ fun yín nígbà tí ó wà ní Galili pé, ‘Dandan ni kí á fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan burúkú lọ́wọ́, kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu, ati pé kí ó jí dìde ní ọjọ́ kẹta.’ ” Wọ́n wá ranti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá kúrò ní ibojì náà, wọ́n pada lọ sọ gbogbo nǹkan tí wọ́n rí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati gbogbo àwọn yòókù. Maria Magidaleni, ati Joana, ati Maria ìyá Jakọbu ati gbogbo àwọn yòókù tí ó bá wọn lọ, ni wọ́n sọ nǹkan wọnyi fún àwọn aposteli. Ṣugbọn bíi ìsọkúsọ ni gbogbo ọ̀rọ̀ yìí rí létí wọn. Wọn kò gba ohun tí àwọn obinrin náà sọ gbọ́. [ Ṣugbọn Peteru dìde, ó sáré lọ sí ibojì náà. Nígbà tí ó yọjú wo inú rẹ̀, aṣọ funfun tí wọ́n fi wé òkú nìkan ni ó rí. Ó bá pada sí ilé, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀.] Ní ọjọ́ kan náà, àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń lọ sí abúlé kan tí ó ń jẹ́ Imausi. Ó tó bí ibùsọ̀ meje sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń bá ara wọn jíròrò lórí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Bí wọ́n ti ń bá ara wọn jíròrò, tí wọn ń bá ara wọn jiyàn, Jesu alára bá súnmọ́ wọn, ó ń bá wọn rìn lọ. Ṣugbọn ó dàbí ẹni pé a dì wọ́n lójú, wọn kò mọ̀ pé òun ni. Ó bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ bí ẹ ti ń rìn bọ̀? Kí ló dé tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀?” Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kilopasi dá a lóhùn pé, “Ṣé àlejò ni ọ́ ní Jerusalẹmu ni, tí o kò fi mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní ààrin bí ọjọ́ mélòó kan yìí?” Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa ati àwọn ìjòyè wa fà á fún ìdájọ́ ikú, wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Òun ní àwa ti ń retí pé yóo fún Israẹli ní òmìnira. Ati pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọjọ́ kẹta nìyí tí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn àwọn obinrin kan láàrin wa sọ ohun tí ó yà wá lẹ́nu. Wọ́n jí lọ sí ibojì, wọn kò rí òkú rẹ̀. Wọ́n wá ń sọ pé àwọn rí àwọn angẹli tí wọ́n sọ pé ó ti wà láàyè. Ni àwọn kan ninu wa bá lọ sí ibojì. Wọ́n bá gbogbo nǹkan bí àwọn obinrin ti wí, ṣugbọn wọn kò rí òun alára.” Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ! Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.” Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ abúlé tí wọn ń lọ, Jesu ṣe bí ẹni pé ó fẹ́ máa bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀ ẹ́ pupọ pé, “Dúró lọ́dọ̀ wa, ọjọ́ ti lọ, ilẹ̀ ti ṣú.” Ni ó bá bá wọn wọlé, ó dúró lọ́dọ̀ wọn. Nígbà tí ó ń bá wọn jẹun, ó mú burẹdi, ó súre sí i, ó bù ú, ó bá fi fún wọn. Ojú wọn bá là; wọ́n wá mọ̀ pé Jesu ni. Ó bá rá mọ́ wọn lójú. Wọ́n wá ń bá ara wọn sọ pé, “Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú wa lọ́kàn bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà, ati bí ó ti ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ fún wa!” Wọ́n bá dìde lẹsẹkẹsẹ, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati àwọn tí ó wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n péjọ sí, àwọn ni wọ́n wá sọ fún wọn pé, “Oluwa ti jí dìde nítòótọ́, ó ti fara han Simoni.”
Luk 24:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú ìkunra olóòórùn dídùn ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá. Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jesu Olúwa. Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n: Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn angẹli náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrín àwọn òkú? Kò sí níhìn-ín yìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Galili. Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.’ ” Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù. Maria Magdalene, àti Joanna, àti Maria ìyá Jakọbu, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn aposteli. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́. Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe. Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀. Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀. Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ. Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n. Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?” Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro. Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?” Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú. Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀. Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu: Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè. Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́: Kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀. Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú. Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró. Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn. Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!” Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn, Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!”