Luk 23:50-54
Luk 23:50-54 Bibeli Mimọ (YBCV)
Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Josefu, ìgbimọ, enia rere, ati olõtọ, (On kò ba wọn li ohùn ni ìmọ ati iṣe wọn), ara Arimatea, ilu awọn Ju kan, ẹniti on pẹlu nreti ijọba Ọlọrun; Ọkunrin yi tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbati o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ àla dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu okuta, nibiti a kò ti itẹ́ ẹnikẹni si ri. O si ṣe ọjọ Ipalẹmọ: ọjọ isimi si kù si dẹ̀dẹ.
Luk 23:50-54 Yoruba Bible (YCE)
Ọkunrin kan wà ninu àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń jẹ́ Josẹfu. Ó jẹ́ eniyan rere ati olódodo. Òun kò bá wọn lóhùn sí ète tí wọ́n pa, ati ohun tí wọ́n ṣe sí Jesu. Ó jẹ́ ará Arimatia, ìlú kan ní Judia. Ó ń retí ìjọba Ọlọrun. Òun ni ó lọ sọ́dọ̀ Pilatu, tí ó bèèrè òkú Jesu. Ó sọ òkú náà kalẹ̀ lórí agbelebu, ó fi aṣọ funfun wé e, ó bá tẹ́ ẹ sinu ibojì tí wọ́n gbẹ́ sinu àpáta, tí wọn kò ì tíì tẹ́ òkú sí rí. Ọjọ́ náà jẹ̀ Ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́, Ọjọ́ Ìsinmi fẹ́rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Luk 23:50-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́. Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run. Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu. Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí. Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́: ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.