Luk 23:39-56
Luk 23:39-56 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀kan ninu àwọn arúfin tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ ń sọ ìsọkúsọ pé, “Ṣebí ìwọ ni Mesaya! Gba ara rẹ là kí o sì gba àwa náà là!” Ṣugbọn ekeji bá a wí, ó ní, “Ìwọ yìí, o kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ìdájọ́ kan náà ni wọ́n dá fún un bíi tiwa. Ní tiwa, ó tọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí èrè iṣẹ́ wa ni à ń jẹ. Ṣugbọn òun ní tirẹ̀ kò ṣẹ̀ rárá.” Ó bá sọ fún Jesu pé, “Ranti mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jesu bá sọ fún un pé, “Mo wí fún ọ, lónìí yìí ni ìwọ yóo wà pẹlu mi ní ọ̀run rere.” Nígbà tí ó tó bí agogo mejila ọ̀sán, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. Oòrùn kò ràn. Aṣọ ìkélé Tẹmpili ya sí meji. Jesu kígbe, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó mí kanlẹ̀, ó bá kú. Nígbà tí ọ̀gágun náà rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Lóòótọ́, olódodo ni ọkunrin yìí.” Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n péjọ, tí wọn wá wòran, rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wọ́n pada lọ, tí wọ́n káwọ́ lérí pẹlu ìbànújẹ́. Gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ati àwọn obinrin tí wọ́n tẹ̀lé e wá láti Galili, gbogbo wọn dúró lókèèrè, wọ́n ń wo gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Ọkunrin kan wà ninu àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń jẹ́ Josẹfu. Ó jẹ́ eniyan rere ati olódodo. Òun kò bá wọn lóhùn sí ète tí wọ́n pa, ati ohun tí wọ́n ṣe sí Jesu. Ó jẹ́ ará Arimatia, ìlú kan ní Judia. Ó ń retí ìjọba Ọlọrun. Òun ni ó lọ sọ́dọ̀ Pilatu, tí ó bèèrè òkú Jesu. Ó sọ òkú náà kalẹ̀ lórí agbelebu, ó fi aṣọ funfun wé e, ó bá tẹ́ ẹ sinu ibojì tí wọ́n gbẹ́ sinu àpáta, tí wọn kò ì tíì tẹ́ òkú sí rí. Ọjọ́ náà jẹ̀ Ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́, Ọjọ́ Ìsinmi fẹ́rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Àwọn obinrin tí wọn bá Jesu wá láti Galili tẹ̀lé Josẹfu yìí, wọ́n ṣe akiyesi ibojì náà, ati bí a ti ṣe tẹ́ òkú Jesu sinu rẹ̀. Wọ́n bá pada lọ láti lọ tọ́jú turari olóòórùn dídùn ati ìpara tí wọn fi ń tọ́jú òkú. Ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n sinmi gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí.
Luk 23:39-56 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati ọkan ninu awọn arufin ti a gbe kọ́ nfi ṣe ẹlẹyà wipe, Bi iwọ ba ṣe Kristi, gbà ara rẹ ati awa là. Ṣugbọn eyi ekeji dahùn, o mba a wipe, Iwọ kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti iwọ wà ninu ẹbi kanna? Niti wa, nwọn jare nitori ère ohun ti a ṣe li awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi kò ṣe ohun buburu kan. O si wipe, Jesu, ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ. Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ, Loni ni iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise. O si to ìwọn wakati kẹfa ọjọ, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan ọjọ. Õrùn si ṣú õkun, aṣọ ikele ti tẹmpili si ya li agbedemeji. Nigbati Jesu si kigbe li ohùn rara, o ni, Baba, li ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹmí mi le: nigbati o si wi eyi tan, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Nigbati balogun ọrún ri ohun ti o ṣe, o yìn Ọlọrun logo, wipe, Dajudaju olododo li ọkunrin yi. Gbogbo ijọ enia ti o pejọ si iran yi, nigbati nwọn nwò ohun ti nṣe, nwọn a lù ara wọn li õkan àiya, nwọn a si pada. Ati gbogbo awọn ojulumọ̀ rẹ̀, ati awọn obinrin ti ntọ̀ ọ lẹhin lati Galili wá, nwọn duro li òkere, nwọn nwò nkan wọnyi. Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Josefu, ìgbimọ, enia rere, ati olõtọ, (On kò ba wọn li ohùn ni ìmọ ati iṣe wọn), ara Arimatea, ilu awọn Ju kan, ẹniti on pẹlu nreti ijọba Ọlọrun; Ọkunrin yi tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbati o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ àla dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu okuta, nibiti a kò ti itẹ́ ẹnikẹni si ri. O si ṣe ọjọ Ipalẹmọ: ọjọ isimi si kù si dẹ̀dẹ. Ati awọn obinrin, ti nwọn bá a ti Galili wá, ti nwọn si tẹle, nwọn kiyesi ibojì na, ati bi a ti tẹ́ okú rẹ̀ si. Nigbati nwọn si pada, nwọn pèse ohun olõrun didùn ororo ikunra ati turari tutù; nwọn si simi li ọjọ isimi gẹgẹ bi ofin.

Luk 23:39-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.” Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà? Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.” Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.” Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!” Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́. Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì, Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!” Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé. Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí. Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́. Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run. Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu. Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí. Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́: ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀. Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Galili wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsi ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórùn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); Wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.