Luk 23:36-43
Luk 23:36-43 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati awọn ọmọ-ogun pẹlu nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn tọ̀ ọ wá, nwọn nfi ọti kikan fun u, Nwọn si nwipe, Bi iwọ ba ṣe Ọba awọn Ju, gbà ara rẹ là. Nwọn si kọwe akọlé si ìgbèri rẹ̀ ni ède Hellene, ati ti Latini, ati ti Heberu, EYI LI ỌBA AWỌN JU. Ati ọkan ninu awọn arufin ti a gbe kọ́ nfi ṣe ẹlẹyà wipe, Bi iwọ ba ṣe Kristi, gbà ara rẹ ati awa là. Ṣugbọn eyi ekeji dahùn, o mba a wipe, Iwọ kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti iwọ wà ninu ẹbi kanna? Niti wa, nwọn jare nitori ère ohun ti a ṣe li awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi kò ṣe ohun buburu kan. O si wipe, Jesu, ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ. Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ, Loni ni iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.
Luk 23:36-43 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ-ogun náà ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n fún un ní ọtí pé kí ó mu ún. Wọ́n ní, “Bí ìwọ bá ni ọba àwọn Juu, gba ara rẹ là.” Wọ́n kọ àkọlé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí òkè orí rẹ̀ pé, “Èyí ni ọba àwọn Juu.” Ọ̀kan ninu àwọn arúfin tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ ń sọ ìsọkúsọ pé, “Ṣebí ìwọ ni Mesaya! Gba ara rẹ là kí o sì gba àwa náà là!” Ṣugbọn ekeji bá a wí, ó ní, “Ìwọ yìí, o kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ìdájọ́ kan náà ni wọ́n dá fún un bíi tiwa. Ní tiwa, ó tọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí èrè iṣẹ́ wa ni à ń jẹ. Ṣugbọn òun ní tirẹ̀ kò ṣẹ̀ rárá.” Ó bá sọ fún Jesu pé, “Ranti mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jesu bá sọ fún un pé, “Mo wí fún ọ, lónìí yìí ni ìwọ yóo wà pẹlu mi ní ọ̀run rere.”
Luk 23:36-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un. Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.” Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe: èyí ni ọba àwọn júù. Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.” Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà? Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.” Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.” Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!”