Luk 23:32-49

Luk 23:32-49 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nwọn si fà awọn meji lọ pẹlu, awọn arufin, lati pa pẹlu rẹ̀. Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Agbari, nibẹ̀ ni nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn arufin na, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ọkan li ọwọ́ òsi. Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀. Awọn enia si duro nworan. Ati awọn ijoye pẹlu wọn, nwọn nyọ-ṣùti si i, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ki o gbà ara rẹ̀ là, bi iba ṣe Kristi, ayanfẹ Ọlọrun. Ati awọn ọmọ-ogun pẹlu nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn tọ̀ ọ wá, nwọn nfi ọti kikan fun u, Nwọn si nwipe, Bi iwọ ba ṣe Ọba awọn Ju, gbà ara rẹ là. Nwọn si kọwe akọlé si ìgbèri rẹ̀ ni ède Hellene, ati ti Latini, ati ti Heberu, EYI LI ỌBA AWỌN JU. Ati ọkan ninu awọn arufin ti a gbe kọ́ nfi ṣe ẹlẹyà wipe, Bi iwọ ba ṣe Kristi, gbà ara rẹ ati awa là. Ṣugbọn eyi ekeji dahùn, o mba a wipe, Iwọ kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti iwọ wà ninu ẹbi kanna? Niti wa, nwọn jare nitori ère ohun ti a ṣe li awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi kò ṣe ohun buburu kan. O si wipe, Jesu, ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ. Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ, Loni ni iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise. O si to ìwọn wakati kẹfa ọjọ, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan ọjọ. Õrùn si ṣú õkun, aṣọ ikele ti tẹmpili si ya li agbedemeji. Nigbati Jesu si kigbe li ohùn rara, o ni, Baba, li ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹmí mi le: nigbati o si wi eyi tan, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Nigbati balogun ọrún ri ohun ti o ṣe, o yìn Ọlọrun logo, wipe, Dajudaju olododo li ọkunrin yi. Gbogbo ijọ enia ti o pejọ si iran yi, nigbati nwọn nwò ohun ti nṣe, nwọn a lù ara wọn li õkan àiya, nwọn a si pada. Ati gbogbo awọn ojulumọ̀ rẹ̀, ati awọn obinrin ti ntọ̀ ọ lẹhin lati Galili wá, nwọn duro li òkere, nwọn nwò nkan wọnyi.

Luk 23:32-49 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n tún ń fa àwọn arúfin meji kan pẹlu rẹ̀, láti lọ pa wọ́n. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì. Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.” Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn eniyan dúró, wọ́n ń wòran. Àwọn ìjòyè ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé, “O gba àwọn ẹlòmíràn là; gba ara rẹ là bí ìwọ bá ni Mesaya, àyànfẹ́ Ọlọrun.” Àwọn ọmọ-ogun náà ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n fún un ní ọtí pé kí ó mu ún. Wọ́n ní, “Bí ìwọ bá ni ọba àwọn Juu, gba ara rẹ là.” Wọ́n kọ àkọlé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí òkè orí rẹ̀ pé, “Èyí ni ọba àwọn Juu.” Ọ̀kan ninu àwọn arúfin tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ ń sọ ìsọkúsọ pé, “Ṣebí ìwọ ni Mesaya! Gba ara rẹ là kí o sì gba àwa náà là!” Ṣugbọn ekeji bá a wí, ó ní, “Ìwọ yìí, o kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ìdájọ́ kan náà ni wọ́n dá fún un bíi tiwa. Ní tiwa, ó tọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí èrè iṣẹ́ wa ni à ń jẹ. Ṣugbọn òun ní tirẹ̀ kò ṣẹ̀ rárá.” Ó bá sọ fún Jesu pé, “Ranti mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jesu bá sọ fún un pé, “Mo wí fún ọ, lónìí yìí ni ìwọ yóo wà pẹlu mi ní ọ̀run rere.” Nígbà tí ó tó bí agogo mejila ọ̀sán, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. Oòrùn kò ràn. Aṣọ ìkélé Tẹmpili ya sí meji. Jesu kígbe, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó mí kanlẹ̀, ó bá kú. Nígbà tí ọ̀gágun náà rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Lóòótọ́, olódodo ni ọkunrin yìí.” Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n péjọ, tí wọn wá wòran, rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wọ́n pada lọ, tí wọ́n káwọ́ lérí pẹlu ìbànújẹ́. Gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ati àwọn obinrin tí wọ́n tẹ̀lé e wá láti Galili, gbogbo wọn dúró lókèèrè, wọ́n ń wo gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.

Luk 23:32-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn méjì mìíràn bákan náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa. Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.” Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un. Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.” Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe: èyí ni ọba àwọn júù. Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.” Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà? Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.” Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.” Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!” Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́. Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì, Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!” Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé. Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.