Luk 23:27-38
Luk 23:27-38 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé Jesu, pẹlu àwọn obinrin tí wọn ń dárò, tí wọn ń sunkún nítorí rẹ̀. Nígbà tí Jesu yipada sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ má sunkún nítorí tèmi mọ́; ẹkún ara yín ati ti àwọn ọmọ yín ni kí ẹ máa sun. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ẹ óo sọ pé, ‘Àwọn àgàn tí kò bímọ rí, tí wọn kò sì fún ọmọ lọ́mú rí ṣe oríire.’ Nígbà náà ni wọn yóo bẹ̀rẹ̀ sí máa sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ wó lù wá,’ wọ́n óo sì máa sọ fún àwọn òkè kékeré pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀.’ Nítorí bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí fún igi tútù, báwo ni yóo ti rí fún igi gbígbẹ?” Wọ́n tún ń fa àwọn arúfin meji kan pẹlu rẹ̀, láti lọ pa wọ́n. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì. Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.” Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn eniyan dúró, wọ́n ń wòran. Àwọn ìjòyè ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé, “O gba àwọn ẹlòmíràn là; gba ara rẹ là bí ìwọ bá ni Mesaya, àyànfẹ́ Ọlọrun.” Àwọn ọmọ-ogun náà ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n fún un ní ọtí pé kí ó mu ún. Wọ́n ní, “Bí ìwọ bá ni ọba àwọn Juu, gba ara rẹ là.” Wọ́n kọ àkọlé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí òkè orí rẹ̀ pé, “Èyí ni ọba àwọn Juu.”
Luk 23:27-38 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ijọ enia pipọ li o ntọ̀ ọ lẹhin, ati awọn obinrin, ti npohùnrere ẹkún, ti nwọn si nṣe idarò rẹ̀. Ṣugbọn Jesu yiju pada si wọn, o si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ẹ má sọkun fun mi, ṣugbọn ẹ sọkun fun ara nyin, ati fun awọn ọmọ nyin. Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ̀ li eyiti ẹnyin o wipe, Ibukun ni fun àgan, ati fun inu ti kò bímọ ri, ati fun ọmú ti kò funni mu ri. Nigbana ni nwọn o bẹ̀rẹ si iwi fun awọn òke nla pe, Wó lù wa; ati fun awọn òke kekeke pe, Bò wa mọlẹ. Nitori bi nwọn ba nṣe nkan wọnyi sara igi tutù, kili a o ṣe sara gbigbẹ? Nwọn si fà awọn meji lọ pẹlu, awọn arufin, lati pa pẹlu rẹ̀. Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Agbari, nibẹ̀ ni nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn arufin na, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ọkan li ọwọ́ òsi. Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀. Awọn enia si duro nworan. Ati awọn ijoye pẹlu wọn, nwọn nyọ-ṣùti si i, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ki o gbà ara rẹ̀ là, bi iba ṣe Kristi, ayanfẹ Ọlọrun. Ati awọn ọmọ-ogun pẹlu nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn tọ̀ ọ wá, nwọn nfi ọti kikan fun u, Nwọn si nwipe, Bi iwọ ba ṣe Ọba awọn Ju, gbà ara rẹ là. Nwọn si kọwe akọlé si ìgbèri rẹ̀ ni ède Hellene, ati ti Latini, ati ti Heberu, EYI LI ỌBA AWỌN JU.
Luk 23:27-38 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé Jesu, pẹlu àwọn obinrin tí wọn ń dárò, tí wọn ń sunkún nítorí rẹ̀. Nígbà tí Jesu yipada sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ má sunkún nítorí tèmi mọ́; ẹkún ara yín ati ti àwọn ọmọ yín ni kí ẹ máa sun. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ẹ óo sọ pé, ‘Àwọn àgàn tí kò bímọ rí, tí wọn kò sì fún ọmọ lọ́mú rí ṣe oríire.’ Nígbà náà ni wọn yóo bẹ̀rẹ̀ sí máa sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ wó lù wá,’ wọ́n óo sì máa sọ fún àwọn òkè kékeré pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀.’ Nítorí bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí fún igi tútù, báwo ni yóo ti rí fún igi gbígbẹ?” Wọ́n tún ń fa àwọn arúfin meji kan pẹlu rẹ̀, láti lọ pa wọ́n. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì. Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.” Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn eniyan dúró, wọ́n ń wòran. Àwọn ìjòyè ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé, “O gba àwọn ẹlòmíràn là; gba ara rẹ là bí ìwọ bá ni Mesaya, àyànfẹ́ Ọlọrun.” Àwọn ọmọ-ogun náà ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n fún un ní ọtí pé kí ó mu ún. Wọ́n ní, “Bí ìwọ bá ni ọba àwọn Juu, gba ara rẹ là.” Wọ́n kọ àkọlé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí òkè orí rẹ̀ pé, “Èyí ni ọba àwọn Juu.”
Luk 23:27-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún Ṣùgbọ́n Jesu yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín. Nítorí kíyèsi i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fún ni mu rí!’ Nígbà náà ni “ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kéékèèkéé pé, “Yí lù wá!” Sí àwọn òkè ńlá, “Bò wá mọ́lẹ̀!” ’ Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kín ni a ó ṣe sára igi gbígbẹ?” Àwọn méjì mìíràn bákan náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa. Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.” Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un. Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.” Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe: èyí ni ọba àwọn júù.