Luk 22:7-12
Luk 22:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja. O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile? O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀. Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ.
Luk 22:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ọjọ́ Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọ́n níláti pa ẹran àsè Ìrékọjá, Jesu rán Peteru ati Johanu, ó ní, “Ẹ lọ ṣe ìtọ́jú ohun tí a óo fi jẹ àsè Ìrékọjá.” Wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á lọ ṣe ètò sí?” Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ẹ bá wọ inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín. Ẹ tẹ̀lé e, ẹ bá a wọ inú ilé tí ó bá wọ̀. Kí ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ni sọ pé níbo ni yàrá ibi tí òun óo ti jẹ àsè Ìrékọjá pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun wà?’ Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.”
Luk 22:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọjọ́ àìwúkàrà pé, nígbà tí wọ́n ní láti pa ọ̀dọ́-àgùntàn ìrékọjá fún ìrúbọ. Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ.” Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?” Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀, kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ Òun ó sì fi gbàngàn ńlá kan lókè ilé hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”