Luk 22:54-71

Luk 22:54-71 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nwọn si gbá a mu, nwọn si fà a lọ, nwọn si mu u wá si ile olori alufa. Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ lẹhin li òkere. Nigbati nwọn si ti dana larin gbọ̀ngan, ti nwọn si joko pọ̀, Peteru joko larin wọn. Ọmọbinrin kan si ri i bi o ti joko nibi imọlẹ iná na, o si tẹjumọ́ ọ, o ni, Eleyi na wà pẹlu rẹ̀. O si sẹ́, o wipe, Obinrin yi, emi ko mọ̀ ọ. Kò pẹ lẹhin na ẹlomiran si ri i, o ni, Iwọ pẹlu wà ninu wọn. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, Emi kọ. O si to iwọn wakati kan ẹlomiran gidigidi tẹnumọ́ ọ, nwipe, Nitõtọ eleyi na wà pẹlu rẹ̀: nitori ara Galili ni iṣe. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. Lojukanna, bi o ti nwi li ẹnu, akukọ kọ. Oluwa si yipada, o wò Peteru. Peteru si ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi li ẹrinmẹta. Peteru si bọ si ode, o sọkun kikorò. Awọn ọkunrin ti nwọn mu Jesu, si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn lù u. Nigbati nwọn si dì i loju, nwọn lù u niwaju, nwọn mbi i pe, Sọtẹlẹ, tani lù ọ nì? Ati nkan pipọ miran ni nwọn nfi ọ̀rọ-òdi sọ si i. Nigbati ilẹ si mọ́, awọn àgba awọn enia, ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe pejọ, nwọn si fà a wá si ajọ wọn, nwọn nwipe, Bi iwọ ba iṣe Kristi nã, sọ fun wa. O si wi fun wọn pe, Bi mo ba wi fun nyin, ẹnyin ki yio gbagbọ́: Bi mo ba si bi nyin lẽre pẹlu, ẹnyin kì yio da mi lohùn, bẹ̃li ẹnyin kì yio jọwọ mi lọwọ lọ. Ṣugbọn lati isisiyi lọ li Ọmọ-enia yio joko li ọwọ́ ọtún agbara Ọlọrun. Gbogbo wọn si wipe, Iwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọrun bi? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin wipe, emi ni. Nwọn si wipe, Kili awa nfẹ ẹlẹri mọ́ si? Awa tikarawa sá ti gbọ́ li ẹnu ara rẹ̀.

Luk 22:54-71 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n bá mú Jesu, wọ́n fà á lọ sí ilé Olórí Alufaa. Ṣugbọn Peteru ń tẹ̀lé wọn lókèèrè. Àwọn kan dá iná sáàrin agbo-ilé, wọ́n jókòó yí i ká, Peteru náà wà láàrin wọn. Ọmọdebinrin kan wá rí i, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu.” Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!” Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ẹlòmíràn tún rí i, ó ní, “Ìwọ náà wà láàrin wọn.” Ṣugbọn Peteru ní, “Ọkunrin yìí, n kò sí níbẹ̀!” Nígbà tí ó tó bíi wakati kan, ọkunrin kan tún sọ pẹlu ìdánilójú pé, “Láìsí àní-àní ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu, nítorí ará Galili ni.” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Ọkunrin yìí, n kò mọ ohun tí ò ń sọ!” Lẹsẹkẹsẹ, ó fẹ́rẹ̀ ma tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, àkùkọ bá kọ. Oluwa yipada, ó wo Peteru, Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ìwọ yóo sẹ́ mi lẹẹmẹta.” Peteru bá jáde lọ, ó bú sẹ́kún, ó bẹ̀rẹ̀ sí hu gan-an. Àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣọ́ Jesu ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń lù ú. Wọ́n daṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń bi í pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọ oríṣìíríṣìí ìsọkúsọ sí i. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin péjọ, wọ́n fa Jesu lọ siwaju ìgbìmọ̀ wọn. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, ṣé ìwọ ni Mesaya náà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá sọ fun yín, ẹ kò ní gbàgbọ́. Bí mo bá sì bi yín ní ìbéèrè, ẹ kò ní dáhùn. Láti àkókò yìí, Ọmọ-Eniyan yóo jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun Olodumare.” Gbogbo wọn wá bi í pé, “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọrun?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹnu ara yín ni ẹ fi sọ pé, èmi ni.” Ni wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó fẹnu ara rẹ̀ sọ.”

Luk 22:54-71 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè. Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn. Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.” Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.” Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.” Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.” Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò. Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú. Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?” Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, “Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!” Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́; Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ). Ṣùgbọ́n láti ìsinsin yìí lọ ni Ọmọ ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.” Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.” Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ àwa tìkára wa sá à ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”