Luk 22:43-46
Luk 22:43-46 Bibeli Mimọ (YBCV)
Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ. Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ, O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò.
Luk 22:43-46 Yoruba Bible (YCE)
Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.] Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”
Luk 22:43-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀. Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”