Luk 22:41-44
Luk 22:41-44 Yoruba Bible (YCE)
Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [ Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.]
Luk 22:41-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura, Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ.
Luk 22:41-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.