Luk 22:24-27
Luk 22:24-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ijà kan si mbẹ larin wọn, niti ẹniti a kà si olori ninu wọn. O si wi fun wọn pe, Awọn ọba Keferi a ma fẹla lori wọn: a si ma pè awọn alaṣẹ wọn ni olõre. Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ. Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ.
Luk 22:24-27 Yoruba Bible (YCE)
Ìjiyàn kan wà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé ta ni ó jẹ́ ẹni pataki jùlọ. Jesu sọ fún wọn pé, “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn. Àwọn aláṣẹ wọn ni wọ́n ń pè ní olóore wọn. Ṣugbọn tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ẹni tí yóo bá jẹ́ ẹni tí ó ṣe pataki jùlọ ninu yín níláti dàbí ọmọ tí ó kéré jùlọ. Ẹni tí yóo jẹ́ aṣaaju níláti máa ṣe bí iranṣẹ. Nítorí ta ni eniyan pataki? Ẹni tí ó jókòó tí ó ń jẹun ni, tabi ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ? Mo ṣebí ẹni tí ó ń jẹun ni. Ṣugbọn èmi wà láàrin yín bí ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ.
Luk 22:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.