Luk 22:14-34
Luk 22:14-34 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó tó àkókò oúnjẹ, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn aposteli rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ti mú mi lọ́kàn pupọ láti jẹ àsè Ìrékọjá yìí pẹlu yín kí n tó jìyà. Nítorí mo sọ fun yín pé n kò tún ní jẹ ẹ́ mọ́ títí di àkókò tí yóo fi ní ìtumọ̀ tí ó pé ní ìjọba Ọlọrun.” Ó bá mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní, “Ẹ gba èyí, kí ẹ pín in láàrin ara yín. Nítorí mo sọ fun yín pé láti àkókò yìí lọ, n kò tún ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo fi dé.” Ó bá mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú, ó bá fún wọn. Ó ní, “Èyí ni ara mi tí a fun yín. [Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ni ó gbé ife fún wọn lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Ife yìí ni majẹmu titun tí Ọlọrun ba yín dá pẹlu ẹ̀jẹ̀ mi tí a ta sílẹ̀ fun yín.] “Ṣugbọn ṣá o, ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ń bá mi tọwọ́ bọwọ́ níbi oúnjẹ yìí. Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti yan ìpín tirẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé!” Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí wádìí láàrin ara wọn pé ta ni ìbá jẹ́ ninu wọn tí yóo dán irú rẹ̀ wò. Ìjiyàn kan wà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé ta ni ó jẹ́ ẹni pataki jùlọ. Jesu sọ fún wọn pé, “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn. Àwọn aláṣẹ wọn ni wọ́n ń pè ní olóore wọn. Ṣugbọn tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ẹni tí yóo bá jẹ́ ẹni tí ó ṣe pataki jùlọ ninu yín níláti dàbí ọmọ tí ó kéré jùlọ. Ẹni tí yóo jẹ́ aṣaaju níláti máa ṣe bí iranṣẹ. Nítorí ta ni eniyan pataki? Ẹni tí ó jókòó tí ó ń jẹun ni, tabi ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ? Mo ṣebí ẹni tí ó ń jẹun ni. Ṣugbọn èmi wà láàrin yín bí ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ. “Ẹ̀yin ni ẹ dúró tì mí ní gbogbo àkókò ìdánwò mi. Gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti fi ìjọba fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà fi ìjọba fun yín, kí ẹ lè bá mi jẹ, kí ẹ sì bá mi mu ninu ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli mejila. “Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà. Ṣugbọn mo ti gbadura fún ọ Simoni, pé kí igbagbọ rẹ kí ó má yẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá ronupiwada, mu àwọn arakunrin rẹ lọ́kàn le.” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Oluwa, mo ṣetán láti bá ọ wẹ̀wọ̀n, ati láti bá ọ kú.” Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!”
Luk 22:14-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀. O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya: Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun. O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin. Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi ijọba Ọlọrun yio fi de. O si mú akara, nigbati o si ti dupẹ o bu u, o si fifun wọn, o wipe, Eyi li ara mi ti a fifun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. Bẹ̃ gẹgẹ lẹhin onjẹ alẹ, o si mu ago, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun li ẹ̀jẹ mi, ti a ta silẹ fun nyin. Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ọwọ́ ẹniti o fi mi hàn wà pẹlu mi lori tabili. Ọmọ-enia nlọ nitõtọ bi a ti pinnu rẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na nipasẹ ẹniti a gbé ti fi i hàn! Nwọn si bẹ̀rẹ si ibère larin ara wọn, tani ninu wọn ti yio ṣe nkan yi. Ijà kan si mbẹ larin wọn, niti ẹniti a kà si olori ninu wọn. O si wi fun wọn pe, Awọn ọba Keferi a ma fẹla lori wọn: a si ma pè awọn alaṣẹ wọn ni olõre. Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ. Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ. Ẹnyin li awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi. Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi; Ki ẹnyin ki o le mã jẹ, ki ẹnyin ki o si le mã mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori itẹ́, ati ki ẹnyin ki o le mã ṣe idajọ fun awọn ẹ̀ya Israeli mejila. Oluwa si wipe, Simoni, Simoni, sawõ, Satani fẹ lati ni ọ, ki o le kù ọ bi alikama: Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le. O si wi fun u pe, Oluwa, mo mura tan lati bá ọ lọ sinu tubu, ati si ikú. O si wipe, Mo wi fun ọ, Peteru, akukọ ki yio kọ loni ti iwọ o fi sẹ́ mi li ẹrinmẹta pe, iwọ kò mọ̀ mi.
Luk 22:14-34 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó tó àkókò oúnjẹ, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn aposteli rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ti mú mi lọ́kàn pupọ láti jẹ àsè Ìrékọjá yìí pẹlu yín kí n tó jìyà. Nítorí mo sọ fun yín pé n kò tún ní jẹ ẹ́ mọ́ títí di àkókò tí yóo fi ní ìtumọ̀ tí ó pé ní ìjọba Ọlọrun.” Ó bá mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní, “Ẹ gba èyí, kí ẹ pín in láàrin ara yín. Nítorí mo sọ fun yín pé láti àkókò yìí lọ, n kò tún ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo fi dé.” Ó bá mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú, ó bá fún wọn. Ó ní, “Èyí ni ara mi tí a fun yín. [Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ni ó gbé ife fún wọn lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Ife yìí ni majẹmu titun tí Ọlọrun ba yín dá pẹlu ẹ̀jẹ̀ mi tí a ta sílẹ̀ fun yín.] “Ṣugbọn ṣá o, ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ń bá mi tọwọ́ bọwọ́ níbi oúnjẹ yìí. Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti yan ìpín tirẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé!” Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí wádìí láàrin ara wọn pé ta ni ìbá jẹ́ ninu wọn tí yóo dán irú rẹ̀ wò. Ìjiyàn kan wà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé ta ni ó jẹ́ ẹni pataki jùlọ. Jesu sọ fún wọn pé, “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn. Àwọn aláṣẹ wọn ni wọ́n ń pè ní olóore wọn. Ṣugbọn tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ẹni tí yóo bá jẹ́ ẹni tí ó ṣe pataki jùlọ ninu yín níláti dàbí ọmọ tí ó kéré jùlọ. Ẹni tí yóo jẹ́ aṣaaju níláti máa ṣe bí iranṣẹ. Nítorí ta ni eniyan pataki? Ẹni tí ó jókòó tí ó ń jẹun ni, tabi ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ? Mo ṣebí ẹni tí ó ń jẹun ni. Ṣugbọn èmi wà láàrin yín bí ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ. “Ẹ̀yin ni ẹ dúró tì mí ní gbogbo àkókò ìdánwò mi. Gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti fi ìjọba fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà fi ìjọba fun yín, kí ẹ lè bá mi jẹ, kí ẹ sì bá mi mu ninu ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli mejila. “Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà. Ṣugbọn mo ti gbadura fún ọ Simoni, pé kí igbagbọ rẹ kí ó má yẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá ronupiwada, mu àwọn arakunrin rẹ lọ́kàn le.” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Oluwa, mo ṣetán láti bá ọ wẹ̀wọ̀n, ati láti bá ọ kú.” Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!”
Luk 22:14-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn aposteli pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Tinútinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà: Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.” Ó sì gba ago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrín ara yín. Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.” Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé, “Èyí ni ara mí tí a fi fún yín: ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì. Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn.” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè láàrín ara wọn, ta ni nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí. Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi. Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi: Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.” Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama: Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.” Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Peteru, àkùkọ kì yóò kọ lónìí tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”