Luk 21:9-11
Luk 21:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gburó ogun ati idagìri, ẹ máṣe foiya: nitori nkan wọnyi ko le ṣe áìkọ́ṣẹ: ṣugbọn opin na kì iṣe lojukanna. Nigbana li o wi fun wọn pe, Orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: Isẹlẹ nla yio si wà kakiri, ati ìyan ati ajakalẹ arùn; ohun ẹ̀ru, ati àmi nla yio si ti ọrun wá.
Luk 21:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ẹ bá gbúròó ogun ati ìrúkèrúdò, ẹ má jẹ́ kí ó dẹ́rùbà yín. Nítorí dandan ni kí nǹkan wọnyi kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn òpin kò níí tíì dé.” Ó tún fi kún un fún wọn pé “Orílẹ̀-èdè kan yóo máa gbógun ti ekeji, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba kan yóo sì máa gbógun ti ekeji. Ilẹ̀ yóo mì tìtì. Ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo wà ní ibi gbogbo. Ohun ẹ̀rù ati àwọn àmì ńlá yóo hàn lójú ọ̀run.
Luk 21:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.” Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ilẹ̀-rírì ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ohun ẹ̀rù, àti ààmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.