Luk 21:29-38
Luk 21:29-38 Yoruba Bible (YCE)
Ó pa òwe kan fún wọn, ó ní, “Ẹ wo igi ọ̀pọ̀tọ́ ati gbogbo igi yòókù. Nígbà tí ẹ bá rí i, tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn dé. Bẹ́ẹ̀ náà ni, nígbà tí ẹ bá rí i, tí gbogbo nǹkan wọnyi ń ṣẹlẹ̀, ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọrun súnmọ́ tòsí. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí kò ní kọjá lọ kí gbogbo nǹkan wọnyi tó ṣẹ. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ. “Ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má jẹ́ kí ayẹyẹ, tabi ìfiṣòfò, tabi ọtí mímu, ati àníyàn ayé gba ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé lójijì ni ọjọ́ náà yóo dé ba yín bí ìgbà tí tàkúté bá mú ẹran. Nítorí ọjọ́ náà yóo dé bá gbogbo eniyan tí ó wà ní ayé. Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura nígbà gbogbo pé, kí ẹ lè lágbára láti borí gbogbo àwọn ohun tí ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ-Eniyan.” Ní ọ̀sán, Jesu a máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili; lálẹ́, á lọ sùn ní orí Òkè Olifi. Gbogbo eniyan a máa tètè jí láti lọ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili.
Luk 21:29-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi; Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá. “Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.” Lọ́sàn án, Jesu a sì máa kọ́ni ní tẹmpili: lóru, a sì máa jáde lọ í wọ̀ ní òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
Luk 21:29-38 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si pa owe kan fun wọn pe; Ẹ kiyesi igi ọpọtọ, ati si gbogbo igi; Nigbati nwọn ba rúwe, ẹnyin ri i, ẹ si mọ̀ fun ara nyin pe, igba ẹ̀run kù fẹfẹ. Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, ijọba Ọlọrun kù si dẹ̀dẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ. Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọ̀bia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi, ti ọjọ na yio si fi de ba nyin lojijì bi ikẹkun. Nitori bẹni yio de ba gbogbo awọn ti ngbe ori gbogbo ilẹ aiye. Njẹ ki ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura nigbagbogbo, ki ẹ ba le là gbogbo nkan wọnyi ti mbọ̀ wá iṣẹ, ki ẹ si le duro niwaju Ọmọ-enia. Lọsán, a si ma kọ́ni ni tẹmpili; loru, a si ma jade lọ iwọ̀ lori òke ti a npè ni oke Olifi. Gbogbo enia si ntọ̀ ọ wá ni tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, lati gbọ́rọ rẹ̀.