Luk 21:20-38

Luk 21:20-38 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbati ẹnyin ba si ri ti a fi ogun yi Jerusalemu ká, ẹ mọ̀ nigbana pe, isọdahoro rẹ̀ kù si dẹ̀dẹ. Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sá lọ sori òke; ati awọn ti mbẹ larin rẹ̀ ki nwọn jade kuro; ki awọn ti o si mbẹ ni igberiko ki o máṣe wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitori ọjọ ẹsan li ọjọ wọnni, ki a le mu ohun gbogbo ti a ti kọwe rẹ̀ ṣẹ. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! nitoriti ipọnju pipọ yio wà lori ati ibinu si awọn enia wọnyi. Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si dì wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún. Àmi yio si wà li õrùn, ati li oṣupa, ati ni irawọ; ati lori ilẹ aiye idamu fun awọn orilẹ-ede nitori ipaiya ti ariwo; Aiya awọn enia yio ma já fun ibẹru, ati fun ireti nkan wọnni ti mbọ̀ sori aiye: nitori awọn agbara ọrun li a o mì titi. Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla. Ṣugbọn nigbati nkan wọnyi ba bẹ̀rẹ si iṣẹ, njẹ ki ẹ wò òke, ki ẹ si gbé ori nyin soke; nitori idande nyin kù si dẹ̀dẹ. O si pa owe kan fun wọn pe; Ẹ kiyesi igi ọpọtọ, ati si gbogbo igi; Nigbati nwọn ba rúwe, ẹnyin ri i, ẹ si mọ̀ fun ara nyin pe, igba ẹ̀run kù fẹfẹ. Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, ijọba Ọlọrun kù si dẹ̀dẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ. Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọ̀bia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi, ti ọjọ na yio si fi de ba nyin lojijì bi ikẹkun. Nitori bẹni yio de ba gbogbo awọn ti ngbe ori gbogbo ilẹ aiye. Njẹ ki ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura nigbagbogbo, ki ẹ ba le là gbogbo nkan wọnyi ti mbọ̀ wá iṣẹ, ki ẹ si le duro niwaju Ọmọ-enia. Lọsán, a si ma kọ́ni ni tẹmpili; loru, a si ma jade lọ iwọ̀ lori òke ti a npè ni oke Olifi. Gbogbo enia si ntọ̀ ọ wá ni tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, lati gbọ́rọ rẹ̀.

Luk 21:20-38 Yoruba Bible (YCE)

“Nígbà tí ẹ bá rí i tí ogun yí ìlú Jerusalẹmu ká, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tí yóo di ahoro súnmọ́ tòsí. Nígbà náà kí àwọn tí ó bá wà ní Judia sálọ sórí òkè. Kí àwọn tí ó bá wà ninu ìlú sá kúrò níbẹ̀. Kí àwọn tí ó bá wà ninu abúlé má sá wọ inú ìlú lọ. Nítorí àkókò ẹ̀san ni àkókò náà, nígbà tí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ yóo ṣẹ. Àwọn obinrin tí ó lóyún ati àwọn tí ó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ gbé! Nítorí ìdààmú pupọ yóo wà ní ayé, ibinu Ọlọrun yóo wà lórí àwọn eniyan yìí. Idà ni a óo fi pa wọ́n. A óo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn tí kì í ṣe Juu yóo wó ìlú Jerusalẹmu palẹ̀, títí àkókò tí a fi fún wọn yóo fi pé. “Àmì yóo yọ ní ojú oòrùn ati ní ojú òṣùpá ati lára àwọn ìràwọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dààmú nígbà tí wọ́n bá gbọ́ tí òkun ń hó, tí ó ń ru sókè. Àwọn eniyan yóo kú sára nítorí ìbẹ̀rù, nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run ni a óo mì tìtì. Nígbà náà ni wọn óo rí Ọmọ-Eniyan tí óo máa bọ̀ ninu ìkùukùu pẹlu agbára ati ògo ńlá. Ẹ jẹ́ kí inú yín kí ó dùn, kí ẹ wá máa yan, nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, nítorí àkókò òmìnira yín ni ó súnmọ́ tòsí.” Ó pa òwe kan fún wọn, ó ní, “Ẹ wo igi ọ̀pọ̀tọ́ ati gbogbo igi yòókù. Nígbà tí ẹ bá rí i, tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn dé. Bẹ́ẹ̀ náà ni, nígbà tí ẹ bá rí i, tí gbogbo nǹkan wọnyi ń ṣẹlẹ̀, ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọrun súnmọ́ tòsí. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí kò ní kọjá lọ kí gbogbo nǹkan wọnyi tó ṣẹ. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ. “Ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má jẹ́ kí ayẹyẹ, tabi ìfiṣòfò, tabi ọtí mímu, ati àníyàn ayé gba ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé lójijì ni ọjọ́ náà yóo dé ba yín bí ìgbà tí tàkúté bá mú ẹran. Nítorí ọjọ́ náà yóo dé bá gbogbo eniyan tí ó wà ní ayé. Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura nígbà gbogbo pé, kí ẹ lè lágbára láti borí gbogbo àwọn ohun tí ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ-Eniyan.” Ní ọ̀sán, Jesu a máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili; lálẹ́, á lọ sùn ní orí Òkè Olifi. Gbogbo eniyan a máa tètè jí láti lọ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili.

Luk 21:20-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún. “Ààmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.” Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi; Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá. “Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.” Lọ́sàn án, Jesu a sì máa kọ́ni ní tẹmpili: lóru, a sì máa jáde lọ í wọ̀ ní òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.