Luk 21:1-28

Luk 21:1-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI o si gbé oju soke, o ri awọn ọlọrọ̀ nfi ẹ̀bun wọn sinu apoti iṣura. O si ri talakà opó kan pẹlu, o nsọ owo-idẹ wẹ́wẹ meji sibẹ. O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, talakà opó yi fi si i jù gbogbo wọn lọ: Nitori gbogbo awọn wọnyi fi sinu ẹ̀bun Ọlọrun lati ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aìni rẹ̀ o sọ gbogbo ohun ini rẹ̀ ti o ni sinu rẹ̀. Bi awọn kan si ti nsọ̀rọ ti tẹmpili, bi a ti fi okuta daradara ati ẹ̀bun ṣe e li ọṣọ, o ní, Ohun ti ẹnyin nwò wọnyi, ọjọ mbọ̀ li eyi ti a kì yio fi okuta kan silẹ lori ekeji ti a kì yio wó lulẹ. Nwọn si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? ati àmi kini yio wà, nigbati nkan wọnyi yio fi ṣẹ? O si wipe, Ẹ mã kiyesara, ki a má bà mu nyin ṣina: nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, ti yio mã wipe, Emi ni Kristi; akokò igbana si kù si dẹ̀dẹ: ẹ máṣe tọ̀ wọn lẹhin. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gburó ogun ati idagìri, ẹ máṣe foiya: nitori nkan wọnyi ko le ṣe áìkọ́ṣẹ: ṣugbọn opin na kì iṣe lojukanna. Nigbana li o wi fun wọn pe, Orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: Isẹlẹ nla yio si wà kakiri, ati ìyan ati ajakalẹ arùn; ohun ẹ̀ru, ati àmi nla yio si ti ọrun wá. Ṣugbọn ṣaju gbogbo nkan wọnyi, nwọn o nawọ́ mu nyin, nwọn o si ṣe inunibini si nyin, nwọn o fi nyin le awọn oni-sinagogu lọwọ, ati sinu tubu, nwọn o mu nyin lọ sọdọ awọn ọba ati awọn ijoye nitori orukọ mi. Yio si pada di ẹrí fun nyin. Nitorina ẹ pinnu rẹ̀ li ọkàn nyin pe ẹ kì yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun. Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju. A o si fi nyin hàn lati ọdọ awọn õbi nyin wá, ati awọn arakunrin, ati awọn ibatan, ati awọn ọrẹ́ wá; nwọn o si mu ki a pa ninu nyin. A o si korira nyin lọdọ gbogbo enia nitori orukọ mi. Ṣugbọn irun ori nyin kan kì o ṣegbé. Ninu sũru nyin li ẹnyin o jère ọkàn nyin. Nigbati ẹnyin ba si ri ti a fi ogun yi Jerusalemu ká, ẹ mọ̀ nigbana pe, isọdahoro rẹ̀ kù si dẹ̀dẹ. Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sá lọ sori òke; ati awọn ti mbẹ larin rẹ̀ ki nwọn jade kuro; ki awọn ti o si mbẹ ni igberiko ki o máṣe wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitori ọjọ ẹsan li ọjọ wọnni, ki a le mu ohun gbogbo ti a ti kọwe rẹ̀ ṣẹ. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! nitoriti ipọnju pipọ yio wà lori ati ibinu si awọn enia wọnyi. Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si dì wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún. Àmi yio si wà li õrùn, ati li oṣupa, ati ni irawọ; ati lori ilẹ aiye idamu fun awọn orilẹ-ede nitori ipaiya ti ariwo; Aiya awọn enia yio ma já fun ibẹru, ati fun ireti nkan wọnni ti mbọ̀ sori aiye: nitori awọn agbara ọrun li a o mì titi. Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla. Ṣugbọn nigbati nkan wọnyi ba bẹ̀rẹ si iṣẹ, njẹ ki ẹ wò òke, ki ẹ si gbé ori nyin soke; nitori idande nyin kù si dẹ̀dẹ.

Luk 21:1-28 Yoruba Bible (YCE)

Bí Jesu ti gbé ojú sókè ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ bí wọ́n ti ń dá owó ọrẹ wọn sinu àpótí ìṣúra. Ó wá rí talaka opó kan, tí ó fi kọbọ meji sibẹ. Ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, owó ọrẹ talaka opó yìí ju ti gbogbo àwọn yòókù lọ. Nítorí gbogbo àwọn yòókù mú ọrẹ wá ninu ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ní; ṣugbọn òun tí ó jẹ́ aláìní, ó mú gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀ wá.” Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa Tẹmpili, wọ́n ń sọ nípa àwọn òkúta dáradára tí wọ́n fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ ati ọrẹ tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Jesu bá dáhùn pé, “Ẹ rí gbogbo nǹkan wọnyi, ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí kò ní sí òkúta kan lórí ekeji tí a kò ní wó lulẹ̀.” Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, nígbà wo ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ. Kí ni yóo sì jẹ́ àmì nígbà tí wọn yóo bá fi ṣẹ?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí á má ṣe tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo wí pé, ‘Èmi ni Mesaya’ ati pé, ‘Àkókò náà súnmọ́ tòsí.’ Ẹ má tẹ̀lé wọn. Nígbà tí ẹ bá gbúròó ogun ati ìrúkèrúdò, ẹ má jẹ́ kí ó dẹ́rùbà yín. Nítorí dandan ni kí nǹkan wọnyi kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn òpin kò níí tíì dé.” Ó tún fi kún un fún wọn pé “Orílẹ̀-èdè kan yóo máa gbógun ti ekeji, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba kan yóo sì máa gbógun ti ekeji. Ilẹ̀ yóo mì tìtì. Ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo wà ní ibi gbogbo. Ohun ẹ̀rù ati àwọn àmì ńlá yóo hàn lójú ọ̀run. Kí gbogbo èyí tó ṣẹlẹ̀, wọn yóo dojú kọ yín, wọn yóo ṣe inúnibíni si yín. Wọn yóo fà yín lọ sí inú ilé ìpàdé ati sinu ẹ̀wọ̀n. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ọba ati àwọn gomina nítorí orúkọ mi. Anfaani ni èyí yóo jẹ́ fun yín láti jẹ́rìí. Nítorí náà, ẹ má ronú tẹ́lẹ̀ ohun tí ẹ óo sọ láti dáàbò bo ara yín, nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín. Àwọn òbí yín, ati àwọn arakunrin yín, àwọn ẹbí yín, ati àwọn ọ̀rẹ́ yín, yóo kọ̀ yín, wọn yóo sì pa òmíràn ninu yín. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn irun orí yín kankan kò ní ṣègbé. Ẹ óo gba ọkàn yín là nípa ìdúróṣinṣin yín. “Nígbà tí ẹ bá rí i tí ogun yí ìlú Jerusalẹmu ká, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tí yóo di ahoro súnmọ́ tòsí. Nígbà náà kí àwọn tí ó bá wà ní Judia sálọ sórí òkè. Kí àwọn tí ó bá wà ninu ìlú sá kúrò níbẹ̀. Kí àwọn tí ó bá wà ninu abúlé má sá wọ inú ìlú lọ. Nítorí àkókò ẹ̀san ni àkókò náà, nígbà tí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ yóo ṣẹ. Àwọn obinrin tí ó lóyún ati àwọn tí ó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ gbé! Nítorí ìdààmú pupọ yóo wà ní ayé, ibinu Ọlọrun yóo wà lórí àwọn eniyan yìí. Idà ni a óo fi pa wọ́n. A óo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn tí kì í ṣe Juu yóo wó ìlú Jerusalẹmu palẹ̀, títí àkókò tí a fi fún wọn yóo fi pé. “Àmì yóo yọ ní ojú oòrùn ati ní ojú òṣùpá ati lára àwọn ìràwọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dààmú nígbà tí wọ́n bá gbọ́ tí òkun ń hó, tí ó ń ru sókè. Àwọn eniyan yóo kú sára nítorí ìbẹ̀rù, nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run ni a óo mì tìtì. Nígbà náà ni wọn óo rí Ọmọ-Eniyan tí óo máa bọ̀ ninu ìkùukùu pẹlu agbára ati ògo ńlá. Ẹ jẹ́ kí inú yín kí ó dùn, kí ẹ wá máa yan, nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, nítorí àkókò òmìnira yín ni ó súnmọ́ tòsí.”

Luk 21:1-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra. Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ: Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.” Bí àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa tẹmpili, bí a ti fi òkúta dáradára àti ẹ̀bùn ṣe é ní ọ̀ṣọ́, fun Ọlọ́run, Jesu wí pé “Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.” Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti ààmì kín ni yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?” Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má bá à mú yín ṣìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kristi náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.” Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ilẹ̀-rírì ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ohun ẹ̀rù, àti ààmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá. “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi. Ẹ o si jẹ́rìí nípa mi. Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú. A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; on ó sì mú kì a pa nínú yín. A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi. Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé. Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín. “Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún. “Ààmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”