Luk 20:1-8
Luk 20:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i, Nwọn si wi fun u pe, Sọ fun wa, aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tabi tali o fun ọ li aṣẹ yi? O si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi pẹlu yio si bi nyin lẽre ọ̀rọ kan; ẹ sọ fun mi. Baptismu ti Johanu, lati ọrun wá ni tabi lọdọ enia? Nwọn si ba ara wọn gbèro wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni; on o wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a gbọ́? Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; gbogbo enia ni yio sọ wa li okuta; nitori nwọn gbagbọ pe, woli ni Johanu. Nwọn si dahùn wipe, nwọn kò mọ̀ ibiti o ti wá. Jesu si wi fun wọn pe, Njẹ emi ki yio wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.
Luk 20:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa irú àṣẹ tí o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi; ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ yìí?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín ní ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run wá ni, tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?” Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ gbogbo àwọn eniyan yóo sọ wá ní òkúta pa, nítorí wọ́n gbà dájú pé wolii ni Johanu.” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “A kò mọ ibi tí ó ti wá.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fún yín.”
Luk 20:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìhìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i. Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?” Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi. Ìtẹ̀bọmi Johanu, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?” Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun yóò wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Johanu.” Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.” Jesu sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”