Luk 2:8-11
Luk 2:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbé. Sá si kiyesi i, angẹli Oluwa na yọ si wọn, ogo Oluwa si ràn yi wọn ká: ẹ̀ru si ba wọn gidigidi. Angẹli na si wi fun wọn pe, Má bẹ̀ru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ̀ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo. Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa.
Luk 2:8-11 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà, àwọn olùṣọ́-aguntan wà ní pápá, níbi tí wọn ń ṣọ́ aguntan wọn ní òru. Angẹli Oluwa kan bá yọ sí wọn, ògo Oluwa tan ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an. Ṣugbọn angẹli náà wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ ńlá fun yín wá, ayọ̀ tí yóo jẹ́ ti gbogbo eniyan. Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya.
Luk 2:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé. Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa.