Luk 2:39-52

Luk 2:39-52 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbati nwọn si ti ṣe nkan gbogbo tan gẹgẹ bi ofin Oluwa, nwọn pada lọ si Galili, si Nasareti ilu wọn. Ọmọ na si ndàgba, o si nlagbara, o si kún fun ọgbọn: ore-ọfẹ Ọlọrun si mbẹ lara rẹ̀. Awọn õbi rẹ̀ a si mã lọ si Jerusalemu li ọdọdún si ajọ irekọja. Nigbati o si di ọmọ ọdún mejila, nwọn goke lọ si Jerusalemu gẹgẹ bi iṣe ajọ na. Nigbati ọjọ wọn si pé bi nwọn ti npada bọ̀, ọmọ na Jesu duro lẹhin ni Jerusalemu; Josefu ati iya rẹ̀ kò mọ̀. Ṣugbọn nwọn ṣebi o wà li ẹgbẹ èro, nwọn rìn ìrin ọjọ kan; nwọn wá a kiri ninu awọn ará ati awọn ojulumọ̀ wọn. Nigbati nwọn kò si ri i, nwọn pada si Jerusalemu, nwọn nwá a kiri. O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta nwọn ri i ninu tẹmpili o joko li arin awọn olukọni, o ngbọ́ ti wọn, o si mbi wọn lẽre. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ fun oyé ati idahùn rẹ̀. Nigbati nwọn si ri i, hà ṣe wọn: iya rẹ̀ si bi i pe, Ọmọ, ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃? sawò o, baba rẹ ati emi ti nfi ibinujẹ wá ọ kiri. O si dahùn wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá mi kiri? ẹnyin kò mọ pe, emi kò le ṣàima wà nibi iṣẹ Baba mi? Ọrọ ti o sọ kò si yé wọn. O si ba wọn sọkalẹ lọ si Nasareti, o si fi ara balẹ fun wọn: ṣugbọn iya rẹ̀ pa gbogbo nkan wọnyi mọ́ ninu ọkàn rẹ̀. Jesu si npọ̀ li ọgbọ́n, o si ndàgba, o si wà li ojurere li ọdọ Ọlọrun ati enia.

Luk 2:39-52 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí gbogbo nǹkan wọnyi tán gẹ́gẹ́ bí òfin Oluwa, wọ́n pada lọ sí Nasarẹti ìlú wọn ní ilẹ̀ Galili. Ọmọ náà ń dàgbà, ó ń lágbára, ó kún fún ọgbọ́n, ojurere Ọlọrun sì wà pẹlu rẹ̀. Àwọn òbí Jesu a máa lọ sí Àjọ̀dún Ìrékọjá ní Jerusalẹmu ní ọdọọdún. Nígbà tí Jesu di ọmọ ọdún mejila, wọ́n lọ sí àjọ yìí gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Nígbà tí àjọ̀dún parí, tí wọn ń pada lọ sí ilé, ọmọde náà, Jesu, dúró ní Jerusalẹmu, ṣugbọn àwọn òbí rẹ̀ kò fura. Wọ́n ṣebí ó wà láàrin ọ̀pọ̀ eniyan tí ń kọ́wọ̀ọ́ rìn ni. Lẹ́yìn tí wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri láàrin àwọn mọ̀lẹ́bí ati àwọn ojúlùmọ̀ wọn. Nígbà tí wọn kò rí i, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, wọ́n rí i ninu Tẹmpili, ó jókòó láàrin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, òun náà sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè. Ẹnu ya gbogbo àwọn tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye rẹ̀ ati nítorí bí ó ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bi í. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rí i, ẹnu yà wọ́n. Ìyá rẹ̀ bá bi í pé, “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Èmi ati baba rẹ dààmú pupọ nígbà tí à ń wá ọ.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá mi kiri? Ẹ kò mọ̀ pé dandan ni fún mi kí n wà ninu ilé Baba mi?” Gbolohun tí ó sọ fún wọn yìí kò sì yé wọn. Ó bá bá wọn lọ sí Nasarẹti, ó sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Ìyá rẹ̀ pa gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi mọ́ ní ọkàn rẹ̀. Bí Jesu ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n rẹ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì ń bá ojurere Ọlọrun ati ti àwọn eniyan pàdé.

Luk 2:39-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn. Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀. Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá. Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà. Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn. Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n: ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.” Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?” Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn. Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀. Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.