Luk 2:15-17
Luk 2:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati awọn angẹli na pada kuro lọdọ wọn lọ si ọrun, awọn ọkunrin oluṣọ-agutan na ba ara wọn sọ pe, Ẹ jẹ ki a lọ tàra si Betlehemu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa fihàn fun wa. Nwọn si wá lọgan, nwọn si ri Maria, ati Josefu, ati ọmọ-ọwọ na, o dubulẹ ninu ibujẹ ẹran. Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi.
Luk 2:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí àwọn angẹli náà ti pada kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-aguntan ń sọ láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtilẹhẹmu tààrà, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tí Oluwa bùn wá gbọ́.” Wọ́n bá yára lọ. Wọ́n wá Maria kàn ati Josẹfu ati ọmọ-ọwọ́ náà tí a tẹ́ sí ibùjẹ ẹran. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sọ ohun gbogbo tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ náà.
Luk 2:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.” Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran. Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí.