Luk 2:11-14
Luk 2:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa. Eyi ni yio si ṣe àmi fun nyin; ẹnyin ó ri ọmọ-ọwọ ti a fi ọja wé, o dubulẹ ni ibujẹ ẹran. Ọpọlọpọ ogun ọrun si yọ si angẹli na li ojijì, nwọn nyìn Ọlọrun, wipe, Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye alafia, ifẹ inu rere si enia.
Luk 2:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya. Àmì tí ẹ óo fi mọ̀ ọ́n nìyí: ẹ óo rí ọmọ-ọwọ́ náà tí wọ́n fi ọ̀já wé, tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.” Lójijì ọpọlọpọ àwọn ogun ọ̀run yọ pẹlu angẹli náà, wọ́n ń yin Ọlọrun pé, “Ògo fún Ọlọrun lókè ọ̀run, alaafia ní ayé fún àwọn tí inú Ọlọrun dùn sí.”
Luk 2:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa. Èyí ni yóò sì ṣe ààmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé, “Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, Àti ní ayé Àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”