Luk 19:45-48
Luk 19:45-48 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o si bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ninu rẹ̀ sode; O si wi fun wọn pe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Ile mi yio jẹ ile adura; ṣugbọn ẹnyin ti sọ ọ di ihò olè. O si nkọ́ni lojojumọ ni tẹmpili. Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn olori awọn enia nwá ọ̀na ati pa a run, Nwọn kò si ri bi nwọn iba ti ṣe: nitori gbogbo enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ̀rọ rẹ̀.
Luk 19:45-48 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu wọ inú Tẹmpili, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tajà jáde. Ó sọ fún wọn pè, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!” Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili lojoojumọ. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin, pẹlu àtìlẹ́yìn àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ń wá ọ̀nà láti pa á, ṣugbọn wọn kò rí ọ̀nà, nítorí gbogbo eniyan ń fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Luk 19:45-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọsa.” Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.