Luk 19:41-44
Luk 19:41-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si sunmọ etile, o ṣijuwò ilu na, o sọkun si i lori, O nwipe, Ibaṣepe iwọ mọ̀, loni yi, ani iwọ, ohun ti iṣe ti alafia rẹ! ṣugbọn nisisiyi nwọn pamọ́ kuro li oju rẹ. Nitori ọjọ mbọ̀ fun ọ, ti awọn ọtá rẹ yio wà yàra ká ọ, nwọn o si yi ọ ká, nwọn o si ká ọ mọ́ niha gbogbo. Nwọn o si wó ọ palẹ bẹrẹ, ati awọn ọmọ rẹ ninu rẹ; nwọn kì yio si fi okuta kan silẹ lori ara wọn; nitoriti iwọ ko mọ̀ ọjọ ìbẹwo rẹ.
Luk 19:41-44 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ etí ìlú, ó wo ìlú náà, ó bá bú sẹ́kún lórí rẹ̀. Ó ní, “Ìbá ti dára tó lónìí, bí o bá mọ̀ lónìí ohun tí ó jẹ́ ọ̀nà alaafia rẹ! Ṣugbọn ó pamọ́ fún ọ. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn ọ̀tá rẹ yóo gbógun tì ọ́, wọn óo yí ọ ká, wọn yóo há ọ mọ́ yípo. Wọn yóo wó ọ lulẹ̀, wọn yóo sì pa àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ. Wọn kò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ekeji ninu rẹ, nítorí o kò fura nígbà tí Ọlọrun wá bẹ̀ ọ́ wò!”
Luk 19:41-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí Àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo. Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”