Luk 19:28-40
Luk 19:28-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o lọ ṣaju, o ngòke lọ si Jerusalemu. O si ṣe, nigbati o sunmọ Betfage on Betaní li òke ti a npè ni Olifi, o rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Wipe, Ẹ lọ iletò ti o kọju si nyin; nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ọ lọ, ẹnyin o ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn ri: ẹ tú u, ki ẹ si fà a wá. Bi ẹnikẹni ba si bi nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú u? ki ẹnyin ki o wi bayi pe, Oluwa ni ifi i ṣe. Awọn ti a rán si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti wi fun wọn. Bi nwọn si ti ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, awọn oluwa rẹ̀ bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú kẹtẹkẹtẹ nì? Nwọn si wipe, Oluwa ni ifi i ṣe. Nwọn si fà a tọ̀ Jesu wá: nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, nwọn si gbé Jesu kà a. Bi o si ti nlọ nwọn tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na. Bi o si ti sunmọ eti ibẹ̀ ni gẹrẹgẹrẹ òke Olifi, gbogbo ijọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si iyọ̀, ati si ifi ohùn rara yìn Ọlọrun, nitori iṣẹ nla gbogbo ti nwọn ti ri; Wipe, Olubukun li Ọba ti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: alafia li ọrun, ati ogo loke ọrun. Awọn kan ninu awọn Farisi li awujọ si wi fun u pe, Olukọni ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi. O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio kigbe soke.
Luk 19:28-40 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí tán ó tẹ̀síwájú, ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ó súnmọ́ ẹ̀bá Bẹtifage ati Bẹtani, ní apá òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ó wà ní ọ̀kánkán yìí. Nígbà tí ẹ bá wọ ibẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ fà á wá. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ Kí ẹ sọ fún un pé, ‘Oluwa nílò rẹ̀ ni.’ ” Àwọn tí ó rán bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí ó ti sọ fún wọn. Nígbà tí wọn ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn oluwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?” Wọ́n sọ fún wọn pé, “Oluwa nílò rẹ̀ ni.” Wọ́n bá fà á lọ sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n tẹ́ ẹ̀wù wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n bá gbé Jesu gùn ún. Bí ó ti ń lọ, wọ́n ń tẹ́ ẹ̀wù wọn sọ́nà. Nígbà tí ó súnmọ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Olifi, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ayọ̀ kígbe sókè, wọ́n ń yin Ọlọrun nítorí gbogbo ohun ńlá tí wọ́n ti rí. Wọ́n ń wí pé, “Aláásìkí ni ẹni tí ó ń bọ̀ bí ọba ní orúkọ Oluwa. Alaafia ní ọ̀run! Ògo ní òkè ọ̀run!” Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Farisi tí wọ́n wà láàrin àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.” Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Mò ń sọ fun yín pé, bí àwọn wọnyi bá dákẹ́, àwọn òkúta yóo kígbe sókè.”
Luk 19:28-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì ti wí nǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ síwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí: ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá. Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ” Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn. Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?” Wọ́n sì wí pé, “Olúwa fẹ́ lò ó.” Wọ́n sì fà á tọ Jesu wá, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sí ẹ̀yìn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì gbé Jesu kà á. Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí; Wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!” “Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!” Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.” Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”