Luk 19:12-27

Luk 19:12-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si wipe, Ọkunrin ọlọlá kan rè ilu òkere lọ igbà ijọba fun ara rẹ̀, ki o si pada. O si pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ mẹwa, o fi mina mẹwa fun wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã ṣowo titi emi o fi de. Ṣugbọn awọn ọlọ̀tọ ilu rẹ̀ korira rẹ̀, nwọn si rán ikọ̀ tẹ̀le e, wipe, Awa kò fẹ ki ọkunrin yi jọba lori wa. O si ṣe, nigbati o gbà ijọba tan, ti o pada de, o paṣẹ pe, ki a pè awọn ọmọ-ọdọ wọnni wá sọdọ rẹ̀, ti on ti fi owo fun nitori ki o le mọ̀ iye ere ti olukuluku fi iṣowo jẹ. Eyi ekini si wá, o wipe, Oluwa, mina rẹ jère mina mẹwa si i. O si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere: nitoriti iwọ ṣe olõtọ li ohun kikini, gbà aṣẹ lori ilu mẹwa. Eyi ekeji si wá, o wipe, Oluwa, mina rẹ jère mina marun. O si wi fun u pẹlu pe, Iwọ joye ilu marun. Omiran si wá, o wipe, Oluwa, wò mina rẹ ti mbẹ li ọwọ́ mi ti mo dì sinu gèle: Nitori mo bẹ̀ru rẹ, ati nitoriti iwọ ṣe onrorò enia: iwọ a ma mu eyi ti iwọ ko fi lelẹ, iwọ a si ma ká eyi ti iwọ kò gbìn. O si wi fun u pe, Li ẹnu ara rẹ na li emi o ṣe idajọ rẹ, iwọ ọmọ-ọdọ buburu. Iwọ mọ̀ pe onrorò enia ni mi, pe, emi a ma mu eyi ti emi ko fi lelẹ emi a si ma ká eyi ti emi ko gbìn; Ẽha si ti ṣe ti iwọ ko fi owo mi si ile elé, nigbati mo ba de, emi iba si bère rẹ̀ ti on ti elé? O si wi fun awọn ti o duro leti ibẹ̀ pe, Ẹ gbà mina na lọwọ rẹ̀, ki ẹ si fi i fun ẹniti o ni mina mẹwa. Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, o ni mina mẹwa. Mo wi fun nyin pe, Ẹnikẹni ti o ni, li a o fifun; ati lọdọ ẹniti kò ni, eyi na ti o ni li a o gbà lọwọ rẹ̀. Ṣugbọn awọn ọtá mi wọnni, ti kò fẹ ki emi ki o jọba lori wọn, ẹ mu wọn wá ihinyi, ki ẹ si pa wọn niwaju mi.

Luk 19:12-27 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà ó sọ fún wọn pé, “Ọkunrin ìjòyè pataki kan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n fẹ́ fi jọba níbẹ̀ kí ó sì pada wálé lẹ́yìn náà Ó bá pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní owó wúrà kọ̀ọ̀kan. Ó ní, ‘Ẹ máa lọ fi ṣòwò kí n tó dé.’ Ṣugbọn àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀ kórìíra rẹ̀. Wọ́n bá rán ikọ̀ ṣiwaju rẹ̀ láti lọ sọ pé àwọn kò fẹ́ kí ọkunrin yìí jọba lórí àwọn! “Nígbà tí ọkunrin yìí jọba tán, tí ó pada dé, ó bá ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó ti fún lówó, kí ó baà mọ èrè tí wọ́n ti jẹ. Ekinni bá dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà kan tí o fún mi pa owó wúrà mẹ́wàá.’ Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ọmọ-ọ̀dọ̀ rere. O ti ṣe olóòótọ́ ninu ohun kékeré. Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’ Ekeji dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà rẹ pa owó wúrà marun-un.’ Oluwa rẹ̀ wí fún òun náà pé, ‘Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú marun-un.’ “Ẹkẹta dé, ó ní, ‘Alàgbà, owó wúrà rẹ nìyí, aṣọ ni mo fi dì í, mo sì fi pamọ́, nítorí mo bẹ̀rù rẹ. Nítorí òǹrorò eniyan ni ọ́. Níbi tí o kò fi nǹkan sí ni o máa ń wá a sí; níbi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o ti máa ń kórè.’ Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ gan-an ni n óo fi ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ burúkú yìí. O mọ̀ pé níbi tí n kò fi nǹkan sí ni mo máa ń wá a sí, ati pé níbi tí n kò fúnrúgbìn sí ni mo ti máa ń kórè. Kí ni kò jẹ́ kí o lọ fi owó mi pamọ́ sí banki, tí ó fi jẹ́ pé bí mo ti dé yìí, ǹ bá gbà á pẹlu èlé?’ “Ó bá sọ fún àwọn tí ó dúró níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó wúrà náà ní ọwọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní owó wúrà mẹ́wàá.’ Wọ́n bá dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, ṣebí òun ti ní owó wúrà mẹ́wàá!’ Ó wá sọ fún wọn pé, ‘Gbogbo ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i. Ọwọ́ ẹni tí kò sì ní, ni a óo ti gba ìba díẹ̀ tí ó ní! Ní ti àwọn ọ̀tá mi wọnyi, àwọn tí kò fẹ́ kí n jọba, ẹ mú wọn wá síhìn-ín, kí ẹ pa wọ́n lójú mi!’ ”

Luk 19:12-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà. Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’ “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’ “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn. “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’ “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’ “Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’ “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’ “Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan; Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn: ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’ “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn; Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’ “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó minas mẹ́wàá.’ “Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mina mẹ́wàá.’ “Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jẹ ọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhín yìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”