Luk 16:14-31

Luk 16:14-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn Farisi, ti nwọn ni ojukokoro si gbọ́ gbogbo nkan wọnyi, nwọn si yọ-ṣùti si i. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun. Ofin ati awọn woli mbẹ titi di igba Johanu: lati igbana wá li a ti nwasu ijọba Ọlọrun, olukuluku si nfi ipá wọ̀ inu rẹ̀. Ṣugbọn o rọrun fun ọrun on aiye lati kọja lọ, jù ki ṣonṣo kan ti ofin ki o yẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé, ẹniti ọkọ rẹ̀ kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga. Njẹ ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o nwọ̀ aṣọ elesè àluko ati aṣọ àla daradara, a si ma jẹ didùndidun lojojumọ́: Alagbe kan si wà ti a npè ni Lasaru, ti nwọn ima gbé wá kalẹ lẹba ọ̀na ile rẹ̀, o kún fun õju, On a si ma fẹ ki a fi ẹrún ti o ti ori tabili ọlọrọ̀ bọ silẹ bọ́ on: awọn ajá si wá, nwọn si fá a li õju lá. O si ṣe, alagbe kú, a si ti ọwọ́ awọn angẹli gbé e lọ si õkan-àiya Abrahamu: ọlọrọ̀ na si kú pẹlu, a si sin i; Ni ipo-oku li o gbé oju rẹ̀ soke, o mbẹ ninu iṣẹ oró, o si ri Abrahamu li òkere, ati Lasaru li õkan-àiya rẹ̀. O si ke, o wipe, Baba Abrahamu, ṣãnu fun mi, ki o si rán Lasaru, ki o tẹ̀ orika rẹ̀ bọmi, ki o si fi tù mi li ahọn; nitori emi njoró ninu ọwọ́ iná yi. Ṣugbọn Abrahamu wipe, Ọmọ, ranti pe, nigba aiye rẹ, iwọ ti gbà ohun rere tirẹ, ati Lasaru ohun buburu: ṣugbọn nisisiyi ara rọ̀ ọ, iwọ si njoro. Ati pẹlu gbogbo eyi, a gbe ọgbun nla kan si agbedemeji awa ati ẹnyin, ki awọn ti nfẹ má ba le rekọja lati ìhin lọ sọdọ nyin, ki ẹnikẹni má si le ti ọ̀hun rekọja tọ̀ wa wá. O si wipe, Njẹ mo bẹ̀ ọ, baba, ki iwọ ki o rán a lọ si ile baba mi: Nitori mo ni arakunrin marun; ki o le rò fun wọn ki awọn ki o má ba wá si ibi oró yi pẹlu. Abrahamu si wi fun u pe, Nwọn ni Mose ati awọn woli; ki nwọn ki o gbọ́ ti wọn. O si wipe, Bẹ̃kọ, Abrahamu baba; ṣugbọn bi ẹnikan ba ti inu okú tọ̀ wọn lọ, nwọn ó ronupiwada. O si wi fun u pe, Bi nwọn kò ba gbọ́ ti Mose ati ti awọn woli, a kì yio yi wọn li ọkan pada bi ẹnikan tilẹ ti inu okú dide.

Luk 16:14-31 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí àwọn Farisi tí wọ́n fẹ́ràn owó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń yínmú sí i. Ó wá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń dá ara yín láre lójú eniyan, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn yín. Ohun tí eniyan ń gbé gẹ̀gẹ̀, ohun ẹ̀gbin ni lójú Ọlọrun. “Ìwé òfin Mose ati ìwé àwọn wolii ni ó wà fún ìlànà títí di àkókò Johanu. Láti ìgbà náà ni a ti ń waasu ìyìn rere ti ìjọba Ọlọrun. Pẹlu ipá sì ni olukuluku fi ń wọ̀ ọ́. Ó rọrùn kí ọ̀run ati ayé kọjá ju pé kí kínńkínní ninu òfin kí ó má ṣẹ lọ. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ tí ó gbé iyawo mìíràn ṣe àgbèrè. Bí ẹnìkan bá sì gbé obinrin tí a ti kọ̀ sílẹ̀ ní iyawo òun náà ṣe àgbèrè. “Ọkunrin kán wà tí ó lówó. Aṣọ àlàárì ati àwọn aṣọ olówó iyebíye mìíràn ni ó máa ń wọ̀. Oúnjẹ àdídùn ni ó máa ń jẹ, lojoojumọ ni ó máa ń se àsè. Talaka kan wà tí ó ń jẹ́ Lasaru, tíí máa ń jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé ọlọ́rọ̀ yìí. Gbogbo ara Lasaru jẹ́ kìkì egbò. Inú rẹ̀ ìbá dùn láti máa jẹ ẹ̀rúnrún tí ó ń bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili olówó yìí. Pẹlu bẹ́ẹ̀ náà, ajá a máa wá lá egbò ara rẹ̀. “Nígbà tí ó yá, talaka yìí kú, àwọn angẹli bá gbé e lọ sọ́dọ̀ Abrahamu. Olówó náà kú, a sì sin ín. Ní ipò òkú ni ó rí ara rẹ̀, tí ó ń joró. Ó wá rí Abrahamu ní òkèèrè pẹlu Lasaru ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó bá pè é, ó ní, ‘Abrahamu, Baba, ṣàánú mi. Rán Lasaru kí ó ti ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó wá kán an sí mi láhọ́n, nítorí mò ń jẹ ìrora ninu iná yìí.’ “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ, ranti pé nígbà tí o wà láyé, kìkì ohun rere ni o gbà, nígbà tí ó jẹ́ pé nǹkan burúkú ni Lasaru gbà. Nisinsinyii, ìdẹ̀ra ti dé bá Lasaru nígbà tí ìwọ ń jẹ̀rora. Ati pé ọ̀gbun ńlá kan wà láàrin àwa ati ẹ̀yin, tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó bá fẹ́ kọjá sí ọ̀dọ̀ yín kò ní lè kọjá; bákan náà àwọn tí ó bá fẹ́ ti ọ̀hún kọjá wá sí ọ̀dọ̀ wa kò ní lè kọjá.’ Olówó náà wá sọ pé, ‘Baba, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, mo bẹ̀ ọ́, rán Lasaru lọ sí ilé baba mi. Arakunrin marun-un ni mo ní; kí ó lọ kìlọ̀ fún wọn kí àwọn náà má baà wá sí ibi oró yìí.’ “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Wọ́n ní ìwé Mose ati ìwé àwọn wolii. Kí wọ́n fetí sí wọn.’ Ṣugbọn ọlọ́rọ̀ náà ní, ‘Ó tì, Abrahamu, Baba! Bí ẹnìkan bá jí dìde ninu òkú, tí ó lọ sọ́dọ̀ wọn, wọn yóo ronupiwada.’ Ṣugbọn Abrahamu sọ fún un pé, ‘Bí wọn kò bá fetí sí ohun tí Mose ati àwọn wolii kọ, bí ẹni tí ó ti kú bá tilẹ̀ jí dìde tí ó lọ bá wọn, kò ní lè yí wọn lọ́kàn pada.’ ”

Luk 16:14-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn Farisi, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ ṣùtì sí i. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni àwọn tí ń dá àre fún ara yín níwájú ènìyàn; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn yín: nítorí ohun ti a gbéga lójú ènìyàn, ìríra ni níwájú Ọlọ́run. “Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Johanu: Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí èyí tí ó kéré jù nínú òfin kí ó yẹ. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé ẹlòmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà: ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé, ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀sílẹ̀ ní ìyàwó náà, ó ṣe panṣágà. “Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ aṣọ elése àlùkò àti aṣọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójoojúmọ́: Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lasaru, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju, Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín; Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’ “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má ba á le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’ “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán Lasaru lọ sí ilé baba mi: Nítorí mo ní arákùnrin márùn-ún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má ba á wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’ “Abrahamu sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’ “Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Abrahamu baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”