Luk 15:25-32
Luk 15:25-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ọmọ rẹ̀ eyi ẹgbọn ti wà li oko: bi o si ti mbọ̀, ti o sunmọ eti ile, o gbọ́ orin on ijó. O si pè ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ wọn, o bère, kili ã mọ̀ nkan wọnyi si? O si wi fun u pe, Aburo rẹ de; baba rẹ si pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa, nitoriti o ri i pada li alafia ati ni ilera. O si binu, o si kọ̀ lati wọle; baba rẹ̀ si jade, o si wá iṣipẹ fun u. O si dahùn o wi fun baba rẹ̀ pe, Wo o, lati ọdún melo wọnyi li emi ti nsin ọ, emi kò si ru ofin rẹ ri: iwọ kò si ti ifi ọmọ ewurẹ kan fun mi, lati fi ba awọn ọrẹ́ mi ṣe ariya: Ṣugbọn nigbati ọmọ rẹ yi de, ẹniti o fi panṣaga run ọrọ̀ rẹ, iwọ si ti pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa fun u. O si wi fun u pe, Ọmọ, nigbagbogbo ni iwọ mbẹ lọdọ mi, ohun gbogbo ti mo si ni, tìrẹ ni. O yẹ ki a ṣe ariya ki a si yọ̀: nitori aburo rẹ yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i.
Luk 15:25-32 Yoruba Bible (YCE)
“Ní gbogbo àkókò yìí, èyí ẹ̀gbọ́n wà ní oko. Bí ó ti ń bọ̀ tí ó ń súnmọ́ etílé, ó gbọ́ ìlù ati ijó. Ó pe ọmọde kan, ó wádìí ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ọmọ yìí bá sọ fún un pé, ‘Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa mààlúù tí ó sanra, ó se àsè nítorí tí àbúrò rẹ pada dé ní alaafia.’ Inú bí èyí ẹ̀gbọ́n, ó bá kọ̀, kò wọlé. Ni baba rẹ̀ bá jáde lọ láti lọ bẹ̀ ẹ́. Ṣugbọn ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Wo ati ọdún tí mo ti ń sìn ọ́, n kò dá àṣẹ rẹ kọjá rí; sibẹ o kò fún mi ni ọmọ ewúrẹ́ kan kí n fi ṣe àríyá pẹlu àwọn ọ̀rẹ́ mi rí. Ṣugbọn nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, àpà ara rẹ̀, tí ó ti run ogún rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn aṣẹ́wó, o wá pa mààlúù tí ó sanra fún un.’ Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ mi, ìwọ wà lọ́dọ̀ mi nígbà gbogbo, gbogbo ohun tí mo ní, tìrẹ ni. Ó yẹ kí á ṣe àríyá, kí á sì máa yọ̀, nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè, ó ti sọnù, a sì tún rí i.’ ”
Luk 15:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko: bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin àti ijó. Ó sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọn, ó béèrè, kín ni a mọ nǹkan wọ̀nyí sí? Ó sì wí fún un pé, ‘Arákùnrin rẹ dé, baba rẹ sì pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa, nítorí tí ó rí i padà ní àlàáfíà àti ní ìlera.’ “Ó sì bínú, ó sì kọ̀ láti wọlé; baba rẹ̀ sì jáde, ó sì wá í ṣìpẹ̀ fún un. Ó sì dáhùn ó wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Wò ó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí: ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá: Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò, ìwọ sì ti pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa fún un.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni. Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí arákùnrin rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”