Luk 15:13-19
Luk 15:13-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna. Nigbati o si bà gbogbo rẹ̀ jẹ tan, ìyan nla wá imu ni ilẹ na; o si bẹ̀rẹ si idi alaini. O si lọ, o da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ̀tọ kan ni ilẹ na; on si rán a lọ si oko rẹ̀ lati tọju ẹlẹdẹ. Ayọ̀ ni iba fi jẹ onjẹ ti awọn ẹlẹdẹ njẹ li ajẹyó: ẹnikẹni kò si fifun u. Ṣugbọn nigbati oju rẹ̀ walẹ, o ni, Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin. Emi o dide, emi o si tọ̀ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ; Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ.
Luk 15:13-19 Yoruba Bible (YCE)
Kò pẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ tí àbúrò yìí fi kó gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó bá lọ sí ìlú òkèèrè, ó sá fi ìwà wọ̀bìà ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá ní ìnákúnàá. Nígbà tí ó ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ tán, ìyàn wá mú pupọ ní ìlú náà, ebi sì bẹ̀rẹ̀ sí pa á. Ni ó bá lọ ń gbé ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀. Ọmọ-ìbílẹ̀ ìlú yìí ba rán an lọ sí oko rẹ̀ láti máa ṣe ìtọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. Ìbá dùn mọ́ ọn láti máa jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kì í fún un ní ohunkohun. Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, ‘Àwọn alágbàṣe baba mi tí wọn ń jẹ oúnjẹ ní àjẹṣẹ́kù kò níye. Èmi wá jókòó níhìn-ín, ebi ń pa mí kú lọ! N óo dìde, n óo tọ baba mi lọ. N óo wí fún un pé, “Baba, mo ti ṣẹ Ọlọrun, mo sì ti ṣẹ ìwọ náà. N kò yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ mọ́. Fi mí ṣe ọ̀kan ninu àwọn alágbàṣe rẹ.” ’
Luk 15:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá. Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní. Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní ‘Mélòó mélòó àwọn alágbàṣe baba mí ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìn-ín. Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ baba mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé: Baba, èmí ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ; Èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.’