Luk 15:11-17
Luk 15:11-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wipe, Ọkunrin kan li ọmọkunrin meji: Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ̀ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pín ohun ìni rẹ̀ fun wọn. Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna. Nigbati o si bà gbogbo rẹ̀ jẹ tan, ìyan nla wá imu ni ilẹ na; o si bẹ̀rẹ si idi alaini. O si lọ, o da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ̀tọ kan ni ilẹ na; on si rán a lọ si oko rẹ̀ lati tọju ẹlẹdẹ. Ayọ̀ ni iba fi jẹ onjẹ ti awọn ẹlẹdẹ njẹ li ajẹyó: ẹnikẹni kò si fifun u. Ṣugbọn nigbati oju rẹ̀ walẹ, o ni, Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin.
Luk 15:11-17 Yoruba Bible (YCE)
Jesu ní, “Ọkunrin kan ní ọmọ meji. Èyí àbúrò sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ogún tèmi tí ó tọ́ sí mi.’ Ni baba bá pín ogún fún àwọn ọmọ mejeeji. Kò pẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ tí àbúrò yìí fi kó gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó bá lọ sí ìlú òkèèrè, ó sá fi ìwà wọ̀bìà ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá ní ìnákúnàá. Nígbà tí ó ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ tán, ìyàn wá mú pupọ ní ìlú náà, ebi sì bẹ̀rẹ̀ sí pa á. Ni ó bá lọ ń gbé ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀. Ọmọ-ìbílẹ̀ ìlú yìí ba rán an lọ sí oko rẹ̀ láti máa ṣe ìtọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. Ìbá dùn mọ́ ọn láti máa jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kì í fún un ní ohunkohun. Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, ‘Àwọn alágbàṣe baba mi tí wọn ń jẹ oúnjẹ ní àjẹṣẹ́kù kò níye. Èmi wá jókòó níhìn-ín, ebi ń pa mí kú lọ!
Luk 15:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì: “Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí.’ Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn. “Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá. Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní. Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní ‘Mélòó mélòó àwọn alágbàṣe baba mí ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìn-ín.