Luk 15:1-7
Luk 15:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBOGBO awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ si sunmọ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀. Ati awọn Farisi ati awọn akọwe nkùn, wipe, ọkunrin yi ngbà ẹlẹṣẹ, o si mba wọn jẹun. O si pa owe yi fun wọn, wipe. Ọkunrin wo ni ninu nyin, ti o ni ọgọrun agutan, bi o ba sọ ọ̀kan nù ninu wọn, ti kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ ni iju, ti kì yio si tọsẹ eyi ti o nù lọ, titi yio fi ri i? Nigbati o si ri i tan, o gbé e le ejika rẹ̀, o nyọ. Nigbati o si de ile, o pè awọn ọrẹ́ ati aladugbo rẹ̀ jọ, o nwi fun wọn pe, Ẹ ba mi yọ̀; nitoriti mo ri agutan mi ti o ti nù. Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ yio wà li ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, jù lori olõtọ mọkandilọgọrun lọ, ti kò ṣe aini ironupiwada.
Luk 15:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá ń kùn; wọ́n ń sọ pé, “Eléyìí ń kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ra, ó tún ń bá wọn jẹun.” Jesu bá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní: “Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan tí ọ̀kan sọnù ninu wọn, ṣé kò ní fi mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ ní pápá, kí ó wá èyí tí ó sọnù lọ títí yóo fi rí i? Nígbà tí ó bá wá rí i, yóo gbé e kọ́ èjìká rẹ̀ pẹlu ayọ̀. Nígbà tí ó bá dé ilé, yóo pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóo wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí aguntan mi tí ó sọnù.’ Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ayọ̀ tí yóo wà ní ọ̀run nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada ju ti ìtorí àwọn olódodo mọkandinlọgọrun-un tí kò nílò ìrònúpìwàdà lọ.
Luk 15:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àti àwọn Farisi àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.” Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé, “Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ̀rún-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò sì tọ ipasẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i? Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀. Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’ Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòtítọ́ mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.