Luk 14:28-32
Luk 14:28-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori tani ninu nyin ti npete ati kọ́ ile-iṣọ, ti kì yio kọ́ joko ki o ṣiro iye owo rẹ̀, bi on ni to ti yio fi pari rẹ̀. Ki o ma ba jẹ pe nigbati o ba fi ipilẹ ile sọlẹ tan, ti kò le pari rẹ̀ mọ́, gbogbo awọn ti o ri i a bẹ̀rẹ si ifi i ṣe ẹlẹyà, Wipe, ọkunrin yi bẹ̀rẹ si ile ikọ́, kò si le pari rẹ̀. Tabi ọba wo ni nlọ ibá ọba miran jà, ti kì yio kọ́ joko, ki o si gbèro bi yio le fi ẹgbarun padegun ẹniti nmu ẹgbawa bọ̀ wá kò on loju? Bi bẹ̃kọ nigbati onitọhun si wà li òkere, on a ran ikọ si i, a si bere ipinhùn alafia.
Luk 14:28-32 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí ta ni ninu yín tí yóo fẹ́ kọ́ ilé ńlá kan, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye tí yóo ná òun, kí ó mọ̀ bí òun bá ní ohun tí òun yóo fi parí rẹ̀? Kí ó má wá jẹ́ pé yóo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ tán, kò ní lè parí rẹ̀ mọ́. Gbogbo àwọn tí ó bá rí i yóo wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọkunrin yìí bẹ̀rẹ̀ ilé, kò lè parí rẹ̀!’ “Tabi ọba wo ni yóo lọ ko ọba mìíràn lójú ogun tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó gba ìmọ̀ràn bí òun yóo bá lè ko ẹni tí ó ní ọ̀kẹ́ kan ọmọ-ogun lójú? Bí kò bá ní lè kò ó lójú, kí ọ̀tá rẹ̀ tó dé ìtòsí, yóo tètè rán ikọ̀ sí i pé òun túúbá.
Luk 14:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀. Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’ “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbàárùn-ún pàdé ẹni tí ń mú ẹgbàáwàá bọ̀ wá ko òun lójú? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlàáfíà.