Luk 14:1-24

Luk 14:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati o wọ̀ ile ọkan ninu awọn olori Farisi lọ li ọjọ isimi lati jẹun, nwọn si nṣọ ọ. Si kiyesi i, ọkunrin kan ti o li asunkun mbẹ niwaju rẹ̀. Jesu si dahùn o wi fun awọn amofin ati awọn Farisi pe, O ha tọ́ lati mu-ni larada li ọjọ isimi, tabi kò tọ? Nwọn si dakẹ. O si mu u, o mu u larada, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ; O si dahùn o wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti kẹtẹkẹtẹ tabi malu rẹ̀ yio bọ sinu ihò, ti kì yio si fà a soke lojukanna li ọjọ isimi? Nwọn kò si le da a li ohùn mọ́ si nkan wọnyi. O si pa owe kan fun awọn ti a pè wá jẹun, nigbati o wò bi nwọn ti nyàn ipò ọlá; o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnikan ba pè ọ wá si ibi iyawo, máṣe joko ni ipò ọlá; ki o ma ba jẹ pe, a pè ẹniti o li ọlá jù ọ lọ. Nigbati ẹniti o pè ọ ati on ba de, a si wi fun ọ pe, Fun ọkunrin yi li àye; iwọ a si wa fi itiju mu ipò ẹhin. Ṣugbọn nigbati a ba pè ọ, lọ ki o si joko ni ipò ẹhin; nigbati ẹniti o pè ọ ba de, ki o le wi fun ọ pe, Ọrẹ́, bọ́ soke: nigbana ni iwọ o ni iyin li oju awọn ti o ba ọ joko ti onjẹ. Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, li a o si gbéga. Nigbana li o si wi fun alase ti o pè e pe, Nigbati iwọ ba se àse ọsán, tabi àse alẹ, má pè awọn ọrẹ́ rẹ, tabi awọn arakunrin rẹ, tabi awọn ibatan rẹ, tabi awọn aladugbo rẹ ọlọrọ̀; nitori ki nwọn ki o má ṣe pè ọ ẹ̀wẹ lati san ẹsan fun ọ. Ṣugbọn nigbati iwọ ba se àse, pè awọn talakà, awọn alabùkù arùn, awọn amukun, ati awọn afọju: Iwọ o si jẹ alabukun fun; nitori nwọn kò ni ohun ti nwọn o fi san a fun ọ: ṣugbọn a o san a fun ọ li ajinde awọn olõtọ. Nigbati ọkan ninu awọn ti o ba a joko tì onjẹ gbọ́ nkan wọnyi, o wi fun u pe, Ibukun ni fun ẹniti yio jẹun ni ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn o wi fun u pe, Ọkunrin kan se àse-alẹ nla, o si pè enia pipọ: O si rán ọmọ-odọ rẹ̀ ni wakati àse-alẹ lati sọ fun awọn ti a ti pè wipe, Ẹ wá; nitori ohun gbogbo ṣe tan. Gbogbo wọn so bẹ̀rẹ, li ohùn kan lati ṣe awawi. Ekini wi fun u pe, Mo rà ilẹ kan, emi kò si le ṣe ki ng má lọ iwò o: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi. Ekeji si wipe, Mo rà ajaga malu marun, mo si nlọ idán wọn wò: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi. Ẹkẹta si wipe, Mo gbeyawo, nitorina li emi kò fi le wá. Ọmọ-ọdọ na si pada de, o sọ nkan wọnyi fun oluwa rẹ̀. Nigbana ni bãle ile binu, o wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Jade lọ si igboro, ati si abuja ọ̀na, ki o si mu awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, ati awọn amukun, ati awọn afọju wá si ihinyi. Ọmọ-ọdọ na si wipe, Oluwa, a ti ṣe bi o ti paṣẹ, àye si mbẹ sibẹ. Oluwa na si wi fun ọmọ-ọdọ na pe, Jade lọ si opópo, ati si ọ̀na ọgbà, ki o si rọ̀ wọn lati wọle wá, ki ile mi le kún. Nitori mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ninu awọn enia wọnyi ti a ti pè, ki yio tọwò ninu àse-alẹ mi.

Luk 14:1-24 Yoruba Bible (YCE)

Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, Jesu lọ jẹun ní ilé ọ̀kan ninu àwọn olóyè láàrin àwọn Farisi. Wọ́n bá ń ṣọ́ ọ. Ọkunrin kan wà níwájú rẹ̀ níbẹ̀ tí gbogbo ara rẹ̀ wú bòmù-bòmù. Jesu bi àwọn amòfin ati àwọn Farisi tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ṣé ó dára láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, tabi kò dára?” Wọ́n bá dákẹ́. Jesu bá mú ọkunrin náà, ó wò ó sàn, ó bá ní kí ó máa lọ. Ó wá bi wọ́n pé, “Ta ni ninu yín tí ọmọ rẹ̀, tabi mààlúù rẹ̀ yóo já sinu kànga ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á yọ lẹsẹkẹsẹ?” Wọn kò sì lè dá a lóhùn. Nígbà tí Jesu ṣe akiyesi bí àwọn tí a pè sí ibi àsè ti ń yan ipò ọlá, ó wá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ sí ibi iyawo, má ṣe lọ jókòó ní ipò ọlá. Bóyá ẹni tí ó pè ọ́ tún pe ẹlòmíràn tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ. Ẹni tí ó pè ọ́ yóo wá tọ̀ ọ́ wá, yóo sọ fún ọ pé, ‘Fi ààyè fún ọkunrin yìí,’ Ìwọ yóo wá fi ìtìjú bẹ̀rẹ̀ sí máa wá ààyè lẹ́yìn. Tí wọn bá pè ọ́, lọ jókòó lẹ́yìn, kí ẹni tí ó pè ọ́ lè wá sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi súnmọ́ iwájú.’ Nígbà náà ìwọ yóo ní iyì lójú gbogbo àwọn tí ó wà níbi àsè. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.” Ó wá sọ fún ẹni tí ó pè é fún oúnjẹ pé, “Nígbà tí o bá se àsè, ìbáà jẹ́ lọ́sàn-án tabi lálẹ́, má ṣe pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tabi àwọn arakunrin rẹ tabi àwọn ẹbí rẹ tabi àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Bí o bá pè wọ́n, àwọn náà yóo pè ọ́ wá jẹun níjọ́ mìíràn, wọn yóo sì san oore tí o ṣe wọ́n pada fún ọ. Ṣugbọn bí o bá se àsè, pe àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú. Èyí ni yóo fún ọ láyọ̀, nítorí wọn kò lè san án pada fún ọ. Ṣugbọn Ọlọrun yóo san án pada fún ọ nígbà tí àwọn olódodo bá jí dìde kúrò ninu òkú.” Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn tí ó wà níbi àsè gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ fún Jesu pé, “Ẹni tí ó bá jẹun ní ìjọba ọ̀run ṣe oríire!” Jesu sọ fún un pé, “Ọkunrin kan se àsè ńlá kan; ó pe ọ̀pọ̀ eniyan sibẹ. Nígbà tí àkókò ati jẹun tó, ó rán iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn tí ó ti pè láti sọ fún wọn pé, ‘Ó yá o! A ti ṣetán!’ Ni gbogbo wọn patapata láìku ẹnìkan bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí. Ekinni sọ fún un pé, ‘Mo ra ilẹ̀ kan, mo sì níláti lọ wò ó. Mo tọrọ àforíjì, yọ̀ǹda mi.’ Ẹnìkejì ní, ‘Mo ra mààlúù fún ẹ̀rọ-ìroko. Mò ń lọ dán an wò, dákun, yọ̀ǹda mi.’ Ẹnìkẹta ní, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé iyawo ni, nítorí náà n kò lè wá.’ “Iranṣẹ náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún oluwa rẹ̀. Inú wá bí baálé ilé náà. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Tètè lọ sí gbogbo títì ati ọ̀nà ẹ̀bùrú ìlú, kí o lọ kó àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú, ati àwọn arọ wá síhìn-ín.’ Nígbà tí iranṣẹ náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, ó ní, ‘Alàgbà, a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, sibẹ àyè tún kù.’ Oluwa iranṣẹ náà sọ fún un pé, ‘Lọ sí ọ̀nà oko, kí o bẹ àwọn ẹni tí o bá rí, kí wọ́n wọlé wá, kí inú ilé mi baà kún. Nítorí kò sí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́kọ́ pè tí yóo tọ́ wò ninu àsè mi!’ ”

Luk 14:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisi lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ. Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ó ní ara wíwú níwájú rẹ̀. Jesu sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisi pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbí kò tọ́?” Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ. Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?” Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí. Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé: “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ. Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní ààyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó ti oúnjẹ. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbéga.” Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú: Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.” Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!” Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀. Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’ “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’ “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’ “Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’ “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’ “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.’ “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún. Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’ ”