Luk 12:41-59

Luk 12:41-59 Bibeli Mimọ (YBCV)

Peteru si wipe, Oluwa, iwọ pa owe yi fun wa, tabi fun gbogbo enia? Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò? Ibukun ni fun ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ti yio ba a ki o ma ṣe bẹ̃. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio si fi i jẹ olori ohun gbogbo ti o ni. Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara; Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́. Ati ọmọ-ọdọ na, ti o mọ̀ ifẹ oluwa rẹ̀, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, on li a o nà pipọ. Ṣugbọn eyi ti kò mọ̀, ti o ṣe ohun ti o yẹ si lilu, on li a o lù niwọn. Nitori ẹnikẹni ti a fun ni pipọ, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère pipọ: lọdọ ẹniti a ba gbé fi pipọ si, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère si i. Iná li emi wá lati fọ̀n si aiye; kili emi si nfẹ bi a ba ti da a ná? Ṣugbọn emi ni baptismu kan ti a o fi baptisi mi; ara ti ń ni mi to titi yio fi pari! Ẹnyin ṣebi alafia li emi wá fi si aiye? mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ; ki a sá kuku pe iyapa: Nitori lati isisiyi lọ, enia marun yio wà ni ile kanna ti a o yà ni ipa, mẹta si meji, ati meji si mẹta. A o yà baba ni ipa si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọkunrin si baba; iya si ọmọbinrin rẹ̀, ati ọmọbinrin si iya rẹ̀; iyakọ si iyawo rẹ̀, ati iyawo si iyako rẹ̀. O si wi fun ijọ enia pẹlu pe, Nigbati ẹnyin ba ri awọsanma ti o ṣú ni ìha ìwọ-õrùn, ọgan ẹnyin a ni, Ọwara òjo mbọ̀; a si ri bẹ̃. Nigbati afẹfẹ gusù ba nfẹ, ẹnyin a ni, Õru yio mu; a si ṣẹ. Ẹnyin agabagebe, ẹnyin le moye oju ọrun ati ti aiye; ẽhatiṣe ti ẹnyin kò le mọ̀ akokò yi? Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin tikara nyin ko fi rò ohun ti o tọ́? Nigbati iwọ ba mbá ọtá rẹ lọ sọdọ olóri, mura li ọ̀na ki a le gbà ọ lọwọ rẹ̀; ki o máṣe fi ọ le onidajọ lọwọ, ki onidajọ máṣe fi ọ le ẹṣọ lọwọ, on a si tì ọ sinu tubu. Ki emi ki o wi fun ọ, iwọ ki yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù.

Luk 12:41-59 Yoruba Bible (YCE)

Peteru wá bi Jesu pé, “Oluwa, àwa ni o pa òwe yìí fún tabi fún gbogbo eniyan?” Oluwa sọ pé, “Ta ni olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹni tí oluwa rẹ̀ fi ṣe olórí àwọn iranṣẹ ilé rẹ̀ pé kí ó máa fún wọn ní oúnjẹ lásìkò. Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ṣe oríire tí oluwa rẹ̀ bá bá a tí ó ń ṣe bí wọ́n ti rán an nígbà tí ó bá dé. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé oluwa rẹ̀ yóo fi ṣe ọ̀gá lórí gbogbo nǹkan tí ó ní. Ṣugbọn bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Yóo pẹ́ kí oluwa mi tó dé,’ tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu, tí ó tún ń mutí yó, ní ọjọ́ tí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà kò retí, ati ní àkókò tí kò rò tẹ́lẹ̀ ni oluwa rẹ̀ yóo dé, yóo kun ún wẹ́lẹwẹ̀lẹ, yóo sì fún un ní ìpín pẹlu àwọn alaiṣootọ. “Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ. Ṣugbọn èyí tí kò bá mọ̀, tí ó bá tilẹ̀ ṣe ohun tí ó fi yẹ kí ó jìyà, ìyà díẹ̀ ni yóo jẹ. Nítorí ẹni tí a bá fún ní nǹkan pupọ, nǹkan pupọ ni a óo retí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹni tí a bá sì fi nǹkan pupọ ṣọ́, nǹkan pupọ ni a óo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. “Iná ni mo wá sọ sí ayé. Ìbá ti dùn tó bí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jó! Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi. Ara mi kò lè balẹ̀ títí yóo fi kọjá. Ẹ má ṣe rò pé alaafia ni mo mú wá sí ayé. Bẹ́ẹ̀ kọ́, ará! Mò ń sọ fun yín, ìyapa ni mo mú wá. Láti ìgbà yìí, ẹni marun-un yóo wà ninu ilé kan, àwọn mẹta yóo lòdì sí àwọn meji; àwọn meji yóo lòdì sí àwọn mẹta. Baba yóo lòdì sí ọmọ, ọmọ yóo lòdì sí baba. Ìyá yóo lòdì sí ọmọ rẹ̀ obinrin, ọmọbinrin yóo lòdì sí ìyá rẹ̀. Ìyakọ yóo lòdì sí iyawo ilé, iyawo ilé yóo lòdì sì ìyakọ rẹ̀.” Jesu tún sọ fún àwọn eniyan pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i tí òjò ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, ẹ óo sọ pé, ‘Òjò yóo rọ̀.’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí. Bí atẹ́gùn bá fẹ́ wá láti gúsù, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ooru yóo mú,’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí. Ẹ̀yin alágàbàgebè! Ẹ mọ àmì ilẹ̀ ati ti ojú sánmà, ṣugbọn ẹ kò mọ àmì àkókò yìí! “Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín kò fi lè mọ ohun tí ó tọ̀nà? Bí o bá ń bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ lọ sí kóòtù, gbìyànjú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹlu rẹ̀ bí ẹ ti ń lọ lọ́nà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́. Onídàájọ́ yóo bá fi ọ́ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́, ni ọlọ́pàá yóo bá tì ọ́ mọ́lé. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé, o kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí o óo fi san gbogbo gbèsè tí o jẹ, láìku kọbọ!”

Luk 12:41-59 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Peteru sì wí pé, “Olúwa, ìwọ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?” Olúwa sì dáhùn wí pé, “Ta ni olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ́n fún wọn ní àkókò? Ìbùkún ni fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín yóò fi jẹ olórí ohun gbogbo tí ó ní. Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, ‘Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀!’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara: Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. “Àti ọmọ ọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀. Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i. “Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé; kín ni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí iná náà ti jo! Ṣùgbọ́n èmi ní bamitiisi kan tí a ó fi bamitiisi mi; ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí! Ẹ̀yin ṣe bí àlàáfíà ni èmi fi sí ayé? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa. Nítorí láti ìsinsin yìí lọ, ènìyàn márùn-ún yóò wà ní ilé kan náà tí a ó yà ní ipa, mẹ́ta sí méjì, àti méjì sí mẹ́ta. A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba; ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.” Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá rí àwọsánmọ̀ tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, ‘Ọ̀wààrà òjò ń bọ̀,’ a sì rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, ‘Oòrùn yóò mú,’ yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin le mòye ojú ọ̀run àti ti ayé. Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò mọ àkókò yìí? “Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin tìkára yín kò fi ro ohun tí ó tọ́? Nígbà tí ìwọ bá bá ọ̀tá rẹ lọ sọ́dọ̀ onídàájọ́, rí i pé o bá a parí ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà kí ó má ba à fà ọ́ fún adájọ́, adájọ́ a fi ọ́ lé ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, òun a sì tì ọ́ sínú túbú. Kí èmi wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀, títí ìwọ ó fi san ẹyọ owó kan tí ó kù!”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa