Luk 12:29-31
Luk 12:29-31 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà, ẹ̀yin ẹ má máa páyà kiri nítorí ohun tí ẹ óo jẹ. (Nítorí pé irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn alaigbagbọ ayé yìí ń dààmú kiri sí.) Baba yín sá mọ̀ pé ẹ nílò wọn. Ṣugbọn kí ẹ máa kọ́kọ́ wá ìjọba rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni yóo fun yín pẹlu.
Luk 12:29-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin.
Luk 12:29-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.