Luk 12:1-3
Luk 12:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe. Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀. Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀.
Luk 12:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè. Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀. Kí ẹ mọ̀ pé ohunkohun tí ẹ sọ ní ìkọ̀kọ̀, a óo gbọ́ nípa rẹ̀ ní gbangba. Ohun tí ẹ bá sọ ninu yàrá, lórí òrùlé ni a óo ti pariwo rẹ̀.
Luk 12:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè. Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀. Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní iyàrá, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.