Luk 11:37-54
Luk 11:37-54 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o si ti nwi, Farisi kan bẹ̀ ẹ ki o ba on jẹun: o si wọle, o joko lati jẹun. Nigbati Farisi na si ri i, ẹnu yà a nitoriti kò kọ́ wẹ̀ ki o to jẹun. Oluwa si wi fun u pe, Ẹnyin Farisi a ma fọ̀ ode ago ati awopọkọ́; ṣugbọn inu nyin kún fun irẹjẹ iwa-buburu. Ẹnyin alaimoye, ẹniti o ṣe eyi ti mbẹ lode, on kọ́ ha ṣe eyi ti mbẹ ninu pẹlu? Ki ẹnyin ki o kuku mã ṣe itọrẹ ãnu ninu ohun ti ẹnyin ni; si kiyesi i, ohun gbogbo li o di mimọ́ fun nyin. Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin a ma san idamẹwa minti, ati rue, ati gbogbo ewebẹ̀, ṣugbọn ẹnyin gbojufò idajọ ati ifẹ Ọlọrun: wọnyi li ẹnyin iba ṣe, ẹ kì ba si ti fi ekeji silẹ laiṣe. Egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin fẹ ipò-ọlá ninu sinagogu, ati ikí-ni li ọjà. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe, ati ẹnyin Farisi, agabagebe! nitoriti ẹnyin dabi isa okú ti kò hàn, awọn enia ti o si nrìn lori wọn kò mọ̀. Nigbana li ọkan ninu awọn amofin dahùn, o si wi fun u pe, Olukọni, li eyi ti iwọ nwi nì iwọ ngàn awa pẹlu. O si wipe, Egbé ni fun ẹnyin amofin pẹlu! nitoriti ẹnyin di ẹrù ti o wuwo lati rù le enia lori, bẹ̃ni ẹnyin tikara nyin kò jẹ fi ika nyin kan kàn ẹrù na. Egbé ni fun nyin! nitoriti ẹnyin kọ́le oju-õrì awọn woli, awọn baba nyin li o si ti pa wọn. Njẹ ẹnyin njẹ ẹlẹri, ẹ si ni inudidun si iṣe awọn baba nyin: nitori nwọn pa wọn, ẹnyin si kọ́le oju-õrì wọn. Nitori eyi li ọgbọ́n Ọlọrun si ṣe wipe, emi ó rán awọn woli ati awọn aposteli si wọn, ninu wọn ni nwọn o si pa, ti nwọn o si ṣe inunibini si: Ki a le bère ẹ̀jẹ awọn woli gbogbo, ti a ti ta silẹ lati igba ipilẹṣẹ aiye wá, lọdọ iran yi; Lati ẹ̀jẹ Abeli wá, titi o si fi de ẹ̀jẹ Sakariah, ti o ṣegbé lãrin pẹpẹ on tẹmpili: lõtọ ni mo wi fun nyin, A o bère rẹ̀ lọdọ iran yi. Egbé ni fun nyin, ẹnyin amofin! nitoriti ẹnyin gbà ọmọ-ṣika ìmọ: ẹnyin tikaranyin kò wọle, awọn ti si nwọle, li ẹnyin kọ̀ fun. Bi o ti nwi nkan wọnyi fun wọn, awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si ibinu si i gidigidi, nwọn si nyọ ọ́ lẹnu lati wi nkan pipọ: Nwọn nṣọ ọ, nwọn nwá ọ̀na ati ri nkan gbámu li ẹnu rẹ̀, ki nwọn ki o le fi i sùn.
Luk 11:37-54 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, Farisi kan pè é pé kí ó wá jẹun ninu ilé rẹ̀. Ó bá wọlé, ó jókòó. Ẹnu ya Farisi náà nígbà tí ó rí i pé Jesu kò kọ́kọ́ wẹwọ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Oluwa wá sọ fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa fọ òde kọ́ọ̀bù ati àwo oúnjẹ, ṣugbọn inú yín kún fún ìwà ipá ati nǹkan burúkú! Ẹ̀yin aṣiwèrè wọnyi! Mo ṣebí ẹni tí ó dá òde, òun náà ni ó dá inú. Ohun kan ni kí ẹ ṣe: ẹ fi àwọn ohun tí ó wà ninu kọ́ọ̀bù ati àwo ṣe ìtọrẹ àánú; bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan di mímọ́ fun yín. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ̀ ń ṣe ìdámẹ́wàá lórí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, gbúre ati oríṣìíríṣìí ewébẹ̀, nígbà tí ẹ kò ka ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ Ọlọrun sí. Àwọn ohun tí ẹ kò kà sí wọnyi ni ó yẹ kí ẹ ṣe, láì gbàgbé àwọn nǹkan yòókù náà. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú ninu ilé ìpàdé. Ẹ tún fẹ́ràn kí eniyan máa ki yín láàrin ọjà. Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.” Ọ̀kan ninu àwọn amòfin sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ báyìí, ò ń fi àbùkù kan àwa náà!” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin amòfin náà gbé! Nítorí ẹ̀ ń di ẹrù bàràkàtà-bàràkàtà lé eniyan lórí nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò jẹ́ fi ọwọ́ yín kan ẹrù kan. Ẹ gbé! Nítorí ẹ̀ ń kọ́ ibojì àwọn wolii, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn baba yín ni wọ́n pa wọ́n. Ṣíṣe tí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fi yín hàn bí ẹlẹ́rìí pé ẹ lóhùn sí ìwà àwọn baba yín: wọ́n pa àwọn wolii, ẹ̀yin wá ṣe ibojì sí ojú-oórì wọn. Ìdí nìyí tí ọgbọ́n Ọlọrun ṣe wí pé, ‘N óo rán àwọn wolii ati àwọn òjíṣẹ́ si yín, ẹ óo pa ninu wọn, ẹ óo ṣe inúnibíni sí àwọn mìíràn.’ Nítorí náà, ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn wolii tí a ti ta sílẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé, ohun tí ó ṣẹ̀ lórí Abeli títí dé orí Sakaraya tí a pa láàrin ibi pẹpẹ ìrúbọ ati Ilé Ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo wọn. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin. Ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ́wọ́, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé. Ẹ tún ń dá àwọn tí ó fẹ́ wọlé dúró!” Nígbà tí Jesu jáde kúrò ninu ilé, àwọn amòfin ati àwọn Farisi takò ó, wọ́n ń bi í léèrè ọ̀rọ̀ pupọ, wọ́n ń dẹ ẹ́ kí wọn lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu.
Luk 11:37-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó sì ti ń wí, Farisi kan bẹ̀ ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun. Nígbà tí Farisi náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun. Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa ń fọ òde ago àti àwopọ̀kọ́: ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ. Ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú? Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín. “Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà. “Ègbé ni fún un yín, (ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisi àgàbàgebè) nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.” Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.” Ó sì wí pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkára yín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà. “Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa. Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn. Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì ṣe wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn aposteli sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’ Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí; láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili: lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò; ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́.” Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀. Wọ́n ń ṣọ́ ọ, wọ́n ń wá ọ̀nà láti rí nǹkan gbámú lẹ́nu kí wọn bá à lè fi ẹ̀sùn kàn án.