Luk 11:27-28
Luk 11:27-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, bi o ti nsọ nkan wọnyi, obinrin kan nahùn ninu ijọ, o si wi fun u pe, Ibukun ni fun inu ti o bí ọ, ati ọmú ti iwọ mu. Ṣugbọn on wipe, Nitõtọ, ki a kuku wipe, Ibukun ni fun awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si pa a mọ́.
Pín
Kà Luk 11Luk 11:27-28 Yoruba Bible (YCE)
Bí Jesu ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, obinrin kan láàrin àwọn eniyan fọhùn sókè pé, “Ẹni tí ó bí ọ, tí ó wò ọ́ dàgbà náà ṣe oríire lọpọlọpọ.” Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Èyí tí ó jù ni pé àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń pa á mọ́ ṣe oríire.”
Pín
Kà Luk 11Luk 11:27-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!” Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”
Pín
Kà Luk 11