Luk 1:8-25

Luk 1:8-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati o nṣe iṣẹ alufa niwaju Ọlọrun ni ipa iṣẹ́ tirẹ̀, Bi iṣe awọn alufa, ipa tirẹ̀ ni ati ma fi turari jóna, nigbati o ba wọ̀ inu tẹmpili Oluwa lọ. Gbogbo ijọ awọn enia si ngbadura lode li akokò sisun turari. Angẹli Oluwa kan si fi ara hàn a, o duro li apa ọtún pẹpẹ turari. Nigbati Sakariah si ri i, ori rẹ̀ wúle, ẹ̀ru si ba a. Ṣugbọn angẹli na wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Sakariah: nitoriti adura rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yio si bí ọmọkunrin kan fun ọ, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Johanu. Iwọ o si li ayọ̀ ati inu didùn: enia pipọ yio si yọ̀ si ibí rẹ̀. Nitori on o pọ̀ niwaju Oluwa, kì yio si mu ọti-waini, bẹ̃ni kì yio si mu ọti-lile; yio si kún fun Ẹmi Mimọ́ ani lati inu iya rẹ̀ wá. On o si pa pipọ da ninu awọn ọmọ Israeli si Oluwa Ọlọrun wọn. Ẹmí ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rẹ̀ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọ́n awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa. Sakariah si wi fun angẹli na pe, Àmi wo li emi o fi mọ̀ eyi? Emi sá di àgba, ati Elisabeti aya mi si di arugbo. Angẹli na si dahùn o wi fun u pe, Emi ni Gabrieli, ti ima duro niwaju Ọlọrun; emi li a rán wá lati sọ fun ọ, ati lati mu ìhin ayọ̀ wọnyi fun ọ wá. Si kiyesi i, iwọ o yadi, iwọ kì yio si le fọhun, titi ọjọ na ti nkan wọnyi yio fi ṣẹ, nitori iwọ ko gbà ọ̀rọ mi gbọ́ ti yio ṣẹ li akokò wọn. Awọn enia si duro dè Sakariah, ẹnu si yà wọn nitoriti o pẹ ninu tẹmpili. Nigbati o si jade, kò le fọhun si wọn: nwọn si woye pe o ri iran ninu tẹmpili: nitoriti o nṣe apẹrẹ si wọn, o si yà odi. O si ṣe, nigbati ọjọ iṣẹ isin rẹ̀ pe, o lọ si ile rẹ̀. Lẹhin ọjọ wọnyi ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyun, o si fi ara rẹ̀ pamọ́ li oṣù marun, o ni, Bayi li Oluwa ṣe fun mi li ọjọ ti o ṣijuwò mi, lati mu ẹ̀gan mi kuro lọdọ araiye.

Luk 1:8-25 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó yá, ó kan ìpín àwọn Sakaraya láti wá ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú Ọlọrun ninu Tẹmpili. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn alufaa, Sakaraya ni ìbò mú láti sun turari ninu iyàrá Tẹmpili Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan ń gbadura lóde ní àkókò tí ó ń sun turari. Angẹli Oluwa kan bá yọ sí i, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ turari. Nígbà tí Sakaraya rí i, ó ta gìrì, ẹ̀rù bà á. Ṣugbọn angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaraya, nítorí pé adura rẹ ti gbà. Elisabẹti iyawo rẹ yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo pe orúkọ rẹ̀ ní Johanu. Ayọ̀ yóo kún ọkàn rẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá ọ yọ̀ nígbà tí ẹ bá bí ọmọ náà. Ọmọ náà yóo jẹ́ ẹni ńlá níwájú Oluwa. Kò gbọdọ̀ mu ọtíkọ́tí, ìbáà jẹ́ líle tabi èyí tí kò le. Yóo kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti ìgbà tí ó bá tí wà ninu ìyá rẹ̀; ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ni yóo sì yipada sí Oluwa Ọlọrun wọn. Òun ni yóo ṣáájú Oluwa pẹlu ẹ̀mí Elija ati agbára rẹ̀. Yóo mú kí àwọn baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu àwọn ọmọ wọn. Yóo yí àwọn alágídí ọkàn pada sí ọ̀nà rere. Yóo sọ àwọn eniyan di yíyẹ lọ́dọ̀ Oluwa.” Sakaraya bi angẹli náà pé, “Báwo ni n óo ti ṣe mọ̀? Nítorí pé mo ti di arúgbó; iyawo mi alára náà sì ti di àgbàlagbà.” Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Geburẹli ni orúkọ mi, èmi ni mo máa ń dúró níwájú Ọlọrun. Ọlọrun ló rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, ati láti sọ nǹkan ayọ̀ yìí fún ọ. Nítorí pé ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, o óo ya odi, o kò ní lè sọ̀rọ̀ títí ọjọ́ tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí yóo ṣẹ nígbà tí ó bá yá.” Àwọn eniyan ti ń retí Sakaraya. Ẹnu yà wọ́n pé ó pẹ́ ninu iyàrá Tẹmpili. Nígbà tí ó jáde, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé ó ti rí ìran ninu iyàrá Tẹmpili ni. Ó yadi, ọwọ́ ni ó fi ń ṣe àpèjúwe fún wọn. Nígbà tí ó parí àkókò tí yóo fi ṣiṣẹ́ alufaa ninu Tẹmpili, ó pada lọ sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Elisabẹti lóyún. Ó bá fi ara pamọ́ fún oṣù marun-un. Ó ní, “Oluwa ni ó ṣe èyí fún mi. Ó ti fi ojú àánú wò mí, ó sì ti mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀gàn fún mi lójú eniyan kúrò.”

Luk 1:8-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run ni àkókò tirẹ̀ Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹmpili Olúwa lọ. Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí. Angẹli Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. Nígbà tí Sekariah sì rí i, orí rẹ̀ wú, ẹ̀rù sì bà á. Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu. Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ. Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá. Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.” Sekariah sì wí fún angẹli náà pé, “Ààmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi sá ti di àgbà, àti Elisabeti aya mi sì di arúgbó.” Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá. Sì kíyèsi i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.” Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sekariah, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹmpili. Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsi wí pé ó ti rí ìran nínú tẹmpili, ó sì ń ṣe àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, Ó sì wí pé “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrín àwọn ènìyàn.”