Luk 1:5-17

Luk 1:5-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigba ọjọ Herodu ọba Judea, alufa kan wà, ni ipa ti Abia, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Sakariah: aya rẹ̀ si ṣe ọkan ninu awọn ọmọbinrin Aaroni, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ Elisabeti. Awọn mejeji si ṣe olododo niwaju Ọlọrun, nwọn nrìn ni gbogbo ofin on ìlana Oluwa li ailẹgan. Ṣugbọn nwọn kò li ọmọ, nitoriti Elisabeti yàgan, awọn mejeji si di arugbo. O si ṣe, nigbati o nṣe iṣẹ alufa niwaju Ọlọrun ni ipa iṣẹ́ tirẹ̀, Bi iṣe awọn alufa, ipa tirẹ̀ ni ati ma fi turari jóna, nigbati o ba wọ̀ inu tẹmpili Oluwa lọ. Gbogbo ijọ awọn enia si ngbadura lode li akokò sisun turari. Angẹli Oluwa kan si fi ara hàn a, o duro li apa ọtún pẹpẹ turari. Nigbati Sakariah si ri i, ori rẹ̀ wúle, ẹ̀ru si ba a. Ṣugbọn angẹli na wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Sakariah: nitoriti adura rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yio si bí ọmọkunrin kan fun ọ, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Johanu. Iwọ o si li ayọ̀ ati inu didùn: enia pipọ yio si yọ̀ si ibí rẹ̀. Nitori on o pọ̀ niwaju Oluwa, kì yio si mu ọti-waini, bẹ̃ni kì yio si mu ọti-lile; yio si kún fun Ẹmi Mimọ́ ani lati inu iya rẹ̀ wá. On o si pa pipọ da ninu awọn ọmọ Israeli si Oluwa Ọlọrun wọn. Ẹmí ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rẹ̀ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọ́n awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa.

Luk 1:5-17 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò Hẹrọdu, ọba Judia, alufaa kan wà tí ń jẹ́ Sakaraya, ní ìdílé Abiya. Orúkọ iyawo rẹ̀ ni Elisabẹti, láti inú ìdílé Aaroni. Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà. Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó. Nígbà tí ó yá, ó kan ìpín àwọn Sakaraya láti wá ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú Ọlọrun ninu Tẹmpili. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn alufaa, Sakaraya ni ìbò mú láti sun turari ninu iyàrá Tẹmpili Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan ń gbadura lóde ní àkókò tí ó ń sun turari. Angẹli Oluwa kan bá yọ sí i, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ turari. Nígbà tí Sakaraya rí i, ó ta gìrì, ẹ̀rù bà á. Ṣugbọn angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaraya, nítorí pé adura rẹ ti gbà. Elisabẹti iyawo rẹ yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo pe orúkọ rẹ̀ ní Johanu. Ayọ̀ yóo kún ọkàn rẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá ọ yọ̀ nígbà tí ẹ bá bí ọmọ náà. Ọmọ náà yóo jẹ́ ẹni ńlá níwájú Oluwa. Kò gbọdọ̀ mu ọtíkọ́tí, ìbáà jẹ́ líle tabi èyí tí kò le. Yóo kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti ìgbà tí ó bá tí wà ninu ìyá rẹ̀; ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ni yóo sì yipada sí Oluwa Ọlọrun wọn. Òun ni yóo ṣáájú Oluwa pẹlu ẹ̀mí Elija ati agbára rẹ̀. Yóo mú kí àwọn baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu àwọn ọmọ wọn. Yóo yí àwọn alágídí ọkàn pada sí ọ̀nà rere. Yóo sọ àwọn eniyan di yíyẹ lọ́dọ̀ Oluwa.”

Luk 1:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà ọjọ́ Herodu ọba Judea, àlùfáà kan wà, láti ìran Abijah, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sekariah: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Aaroni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Elisabeti. Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn. Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Elisabeti yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó. Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run ni àkókò tirẹ̀ Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹmpili Olúwa lọ. Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí. Angẹli Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. Nígbà tí Sekariah sì rí i, orí rẹ̀ wú, ẹ̀rù sì bà á. Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu. Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ. Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá. Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”