Luk 1:46-51
Luk 1:46-51 Bibeli Mimọ (YBCV)
Maria si dahùn, o ni, Ọkàn mi yìn Oluwa logo, Ẹmí mi si yọ̀ si Ọlọrun Olugbala mi. Nitoriti o ṣijuwò ìwa irẹlẹ ọmọbinrin ọdọ rẹ̀: sá wò o, lati isisiyi lọ gbogbo iran enia ni yio ma pè mi li alabukunfun. Nitori ẹniti o li agbara ti ṣe ohun ti o tobi fun mi; mimọ́ si li orukọ rẹ̀. Anu rẹ̀ si mbẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ lati irandiran. O ti fi agbara hàn li apa rẹ̀; o ti tú awọn onirera ká ni ironu ọkàn wọn.
Luk 1:46-51 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Maria sọ pé, “Ọkàn mi gbé Oluwa ga, ẹ̀mí mi yọ̀ sí Ọlọrun, Olùgbàlà mi, nítorí ó ti bojúwo ipò ìrẹ̀lẹ̀ iranṣẹbinrin rẹ̀. Wò ó! Láti ìgbà yìí lọ gbogbo ìran ni yóo máa pè mí ní olóríire. Nítorí Olodumare ti ṣe ohun ńlá fún mi, Mímọ́ ni orúkọ rẹ̀; àánú rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fi agbára rẹ̀ hàn, ó tú àwọn tí ó gbéraga ninu ọkàn wọn ká.
Luk 1:46-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Maria sì dáhùn, ó ní: “Ọkàn mi yin Olúwa lógo, Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi. Nítorí tí ó ṣíjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀: Sá wò ó. Láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún. Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi; Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀. Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ láti ìrandíran. Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀; o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.