Luk 1:26-45

Luk 1:26-45 Bibeli Mimọ (YBCV)

Li oṣù kẹfa a si rán angẹli Gabrieli lati ọdọ Ọlọrun lọ si ilu kan ni Galili, ti a npè ni Nasareti, Si wundia kan ti a fẹ fun ọkunrin kan, ti a npè ni Josefu, ti idile Dafidi; orukọ wundia na a si ma jẹ Maria. Angẹli na si tọ̀ ọ wá, o ni, Alãfia iwọ ẹniti a kọjusi ṣe li ore, Oluwa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin. Ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò lelẹ nitori ọ̀rọ na, o si rò ninu ara rẹ̀ pe, irú kíki kili eyi. Angẹli na si wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Maria: nitori iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun. Sá si kiyesi i, iwọ o lóyun ninu rẹ, iwọ o si bí ọmọkunrin kan, iwọ o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU. On o pọ̀, Ọmọ Ọgá-ogo julọ li a o si ma pè e: Oluwa Ọlọrun yio si fi itẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fun u: Yio si jọba ni ile Jakọbu titi aiye; ijọba rẹ̀ ki yio si ni ipẹkun. Nigbana ni Maria wi fun angẹli na pe, Eyi yio ha ti ṣe ri bẹ̃, nigbati emi kò ti mọ̀ ọkunrin? Angẹli na si dahùn o si wi fun u pe, Ẹmí Mimọ́ yio tọ̀ ọ wá, ati agbara Ọgá-ogo yio ṣiji bò ọ: nitorina ohun mimọ́ ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun li a o ma pè e. Si kiyesi i, Elisabeti ibatan rẹ, on pẹlu si lóyun ọmọkunrin kan li ogbologbo rẹ̀: eyi si li oṣu kẹfa fun ẹniti a npè li agàn. Nitori kò si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe. Maria si wipe, Wò ọmọ-ọdọ Oluwa; ki o ri fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Angẹli na si fi i silẹ lọ. Ni ijọ wọnyi ni Maria si dide, o lọ kánkan si ilẹ-òke, si ilu kan ni Juda; O si wọ̀ ile Sakariah lọ o si ki Elisabeti. O si ṣe, nigbati Elisabeti gbọ́ kikí Maria, ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabeti si kún fun Ẹmí Mimọ́: O si ke li ohùn rara, o si wipe, Alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin, alabukun-fun si ni fun ọmọ inu rẹ. Nibo si li eyi ti wá ba mi, ti iya Oluwa mi iba fi tọ̀ mi wá? Sawò o, bi ohùn kikí rẹ ti bọ́ si mi li etí, ọlẹ̀ sọ ninu mi fun ayọ̀. Alabukun-fun si li ẹniti o gbagbọ́: nitori nkan wọnyi ti a ti sọ fun u lati ọdọ Oluwa wá yio ṣẹ.

Luk 1:26-45 Yoruba Bible (YCE)

Ní oṣù kẹfa, Ọlọrun rán angẹli Geburẹli lọ sí ìlú kan ní Galili tí wọn ń pè ní Nasarẹti. Ọlọrun rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wundia kan tí ó jẹ́ iyawo àfẹ́sọ́nà ọkunrin kan tí ń jẹ́ Josẹfu, ti ìdílé Dafidi. Wundia náà ń jẹ́ Maria. Angẹli náà wọlé tọ Maria lọ, ó kí i, ó ní “Alaafia ni fún ọ! Ìwọ ẹni tí Ọlọrun kọjú sí ṣe ní oore, Oluwa wà pẹlu rẹ.” Nígbà tí Maria gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ó ń rò lọ́kàn rẹ̀ pé, irú kíkí wo nìyí? Angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí o ti bá ojurere Ọlọrun pàdé. O óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan, Jesu ni o óo pe orúkọ rẹ̀. Eniyan ńlá ni yóo jẹ́. Ọmọ Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè é. Oluwa Ọlọrun yóo fún un ní ìtẹ́ Dafidi, baba rẹ̀. Yóo jọba lórí ìdílé Jakọbu títí lae, ìjọba rẹ̀ kò ní lópin.” Maria bá bi angẹli náà pé, “Báwo ni yóo ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí n kò tíì mọ ọkunrin?” Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóo tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá Ògo yóo ṣíji bò ọ́. Nítorí náà Ọmọ Mímọ́ Ọlọrun ni a óo máa pe ọmọ tí ìwọ óo bí. Ati pé Elisabẹti, ìbátan rẹ náà ti lóyún ọmọkunrin kan ní ìgbà ogbó rẹ̀. Ẹni tí wọ́n ti ń pè ní àgàn rí sì ti di aboyún oṣù mẹfa. Nítorí kò sí ohun tí ó ṣòro fún Ọlọrun.” Maria bá dáhùn pé, “Iranṣẹ Oluwa ni mí. Kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà bá fi í sílẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, Maria múra pẹlu ìwàǹwára, ó lọ sí ìlú Judia kan tí ó wà ní agbègbè orí òkè. Ó wọ inú ilé Sakaraya, ó bá kí Elisabẹti. Bí Elisabẹti ti gbọ́ ohùn Maria, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabẹti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó kígbe sókè, ó ní, “Ibukun Ọlọrun wà lórí rẹ pupọ láàrin àwọn obinrin. Ibukun Ọlọrun sì wà lórí ọmọ inú rẹ. Mo ṣe ṣe oríire tó báyìí, tí ìyá Oluwa mi fi wá sọ́dọ̀ mi? Nítorí bí mo ti gbọ́ ohùn rẹ nígbà tí o kí mi, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ inú mi sọ nítorí ó láyọ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ọ nítorí o gba ohun tí Oluwa ti sọ gbọ́, pé yóo ṣẹ.”

Luk 1:26-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti, sí wúńdíá kan tí a ṣèlérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Josẹfu, ti ìdílé Dafidi; orúkọ wúńdíá náà a sì máa jẹ́ Maria. Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.” Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí. Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JESU. Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún: Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.” Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.” Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò ṣíji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é. Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀. Èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn. Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.” Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ. Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea; Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti. Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí mímọ́; Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí. Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá? Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀. Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́: nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa